Joshua Beckford: Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kàwé gboye jáde ni Fasiti Oxford

Joshua
Àkọlé àwòrán, Ṣe ẹ ti gbọ́ ri?, Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kàwé gboye jáde ni fasiti Oxford

Kíì ṣe pé ẹ si mí gbọ́ oo, Joshua Beckford wọ ilé iwé fásiti Oxford ní ọmọ ọdún mẹ́fa.

Gẹ́gẹ́ bi ìròyin ṣe sọ Joshua Beckford ni ààrún to níiṣe pẹ̀lú ọpọlọ.

Joshua Beckford yìí ló kéré jùlọ to ti wọ ilé iwé Oxford ní England, ọmọde náà ni òun setan láti tún ayé ṣe láti di dọkíta oniṣẹ-abẹ ọpọlọ lojúnà ati ran aye lọ́wọ́ lọ́jọ́ kan.

Àkọlé fídíò, Iya Woli: Ẹ̀mí ìjókíjó, Wòó, Ṣọ̀kí, Wojú, Ṣàkùṣákù, One Corner...jáde!

Ọmọ oṣù mẹ́wàá ni Joshua wá nígbà tí bàbá rẹ̀, Knox Daniel sakiyesi pé ọmọ náà kii ṣe ọmọ lásan, nítori ó kàn gbé sori itan lọ́jọ́ kan níwáju Kọmputa ni nigbà ti ọmọ náà ti ha gbogbo àmi ori kọmputa sori.

Àkọlé fídíò, Josh Posh: Inú mi máa ń dùn láti kọrin fún àbúrò mi ní kékeré

Nígba ti Joshua pè ọmọ ọdun mẹ́ta o ti bẹ̀rẹ̀ si ni kàwé geerege tó si ń sọ èdè Japàní, bákan náà lo tí mọ ǹkan kọ sori kọmputa ko to bẹ̀reẹ̀ si ni kọ̀wé pẹ̀lu bírò.

Nígbà ti ó pé ọmọ ọdun mẹ́rin ló ti ń fi kọmpta ṣe ìdánilẹkọọ fún awọn èrò to lé ni ìgbá sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nípa kíkọ wọ́n ni ẹ̀yà àra ènìyàn lásiko ètò ìkowojọ fún kan ni ilú wọ́n.

Àkọlé fídíò, Jeremiah Addo: Ọmọ ọdún méjì tó ṣeeṣe kò mọ̀wé jù l'ágbàáyé

Baba rẹ̀ tilẹ̀ mọ pé ọpọlọ ọmọ náà ti kọja ẹkọ ti ẹgbẹ́ rẹ̀ le kọ, nítori náà ilé ni wọn ti ń kọọ niwe, àti pé kìí fẹ́ báwọ́n ọmọde ẹgbẹ rẹ̀ ṣe bí ko ṣe àwọn àgbá tabi àwọn toi jùú lọ.

Ní ọdun 2011, Daniel tii ṣe baba rẹ gbọ́ nípa àkanṣe ètò kan ti fasiti Oxford ń se fun àwọn ọmọ ọdun mẹjọ sí mẹ́tala.

Nitootọ ọmọ ọdun mẹ́fà ni ọmọ tirẹ̀ nigba naa sùgbọn o fi si ilé ẹko náà láti pe ọpọlọ rẹ̀ níjà.

Johua , iya rẹ ati aburo

Oríṣun àwòrán, @joshua

Àkọlé àwòrán, Ṣe ẹ ti gbọ́ ri?, Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kàwé gboye jáde ni fasiti Oxford

Ọmọ náà ti kopa nínú àwọn oníruuru ìpáde ti àwọn agbaagba àti ọjọgbọn máa ń peju si.

Bayii, Joshua ti ṣetan nile ẹkọ giga fasiti Oxford.

Àkọlé fídíò, Ẹ wo àrà àwọn ọmọ kékeré ń fi ẹ̀kọ́ kọ̀mpútà dá