Igbákejì ààre Osinbajọ yan Tolani Alli gẹ́gẹ́ bíi ayàwòrán rẹ́ tuntun

Tolani Alli

Oríṣun àwòrán, @tolanialli

Àkọlé àwòrán, Iṣẹ tokunrin n ṣe, obirin naa le ṣe e
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Igbakeji aare, Yemi Osinbajo ti yan Tolani Alli, gẹgẹ bi ayaworan rẹ tuntun.

Olubadamọran pataki fun aarẹ Muhammadu Buhari lori iroyin igbalode, Tolu Ogunlesi, lo fi ọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ.

Tolani Alli ni o ti jẹ ayaworan fun gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ ri, Abiola Ajimobi.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Tani Tolani Alli?

Tolani Alli kẹkọọ jade ni Fasiti Michigan, ni orilẹ-ede Amẹrika, nibi ti o ti kẹkọọ nipa imọ sayẹnsi.

O bẹrẹ si nii ya aworan ni ọdun 2010 nigba ti o wa ni ile ẹkọ giga fasiti Michigan.

Tolani jẹ oludari iṣẹ ẹgbẹ awọn ọmọ ilẹ Adulawọ ni fasiti Michigan.

Bakan naa lo tun kọ ẹkọ nipa ilera lọdun 2008 si 2012 ni Michigan Flint

O tun kọ ẹkọ nipa fọto yiya ati iroyin ṣiṣe ni danish School of Media and Journalism Documentary Photography Course.

Lara awọn isẹ ti Tolani Alli ti se tẹlẹ ri ni " Code Girl Magic" eyi o se ni osu kankanla, ọdun 2018.

Tolani Alli

Oríṣun àwòrán, @tolanialli

Oun naa lo tun se " Women in the Delta" ni osu kejila, ọdun 2018.

Tolani jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ Illusions Imagery ki o to di pe igbakeji aare, Yemi Osibanjọ yan si ipo tuntun yi.

Awọn ti Tolani n wo niwaju ni awọn bii Kobe Bryant.

Ọpọlọpọ ami ẹyẹ ni Tolani ti gba lẹnu iṣẹ aworan yiya to yan laayo.

Tolani ti ba arun jẹjẹrẹ pòó, o si ti bori lo fi n figba gbogbo rọ awọn eniyan lati má sọ ireti nu laye.

Tolani ṣiṣẹ gẹgẹ bi ayaworan fun gomina Ajimobi to tukọ ipinlẹ Oyo lati oṣu kejila lọdun 2014 to fi kuro nipo.

Ọpọlopo iṣẹ rẹ lo ti jẹ itẹwọgba nilẹ yii ati loke okun.

Ede yoruba ati ede Gẹẹsi dan lẹnu Tolani daadaa.

Tolani fẹran lati maa wo ere idaraya bọọlu alajusawọn ati ko maa tun ẹrọ kọmputa ṣe tabi ko kuku maa kawe akagbadun ninu ile.

Àkọlé fídíò, Wo imọran Fọlọrunṣọ Alakija fun awọn ọdọ adulawọ