Fraud Allegations: Àjọ FBI mú ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà lórí ẹ̀sùn jìbìtì l'Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Twitter/FBI
Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ orilẹede Amẹrika, FBI sọ pe awọn ti mu ọpọ ọmọ Naijiria ninu iwadii awọn to n lọ lọwọ lori ẹsun jibiti.
Olori eto idajọ nilẹ Amẹrika, Nick Hanna lo fidi ọrọ mu lẹ nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ l'Ọjọbọ.
Hanna ṣalaye pe awọn ọmọ orilẹede Naijiria ọun gbimọ pọ pẹlu awọn aṣoju ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ lati lu awọn kan ni jibiti.
- PFN: Fatoyinbo kọ̀ láti yọjú ni ìwádìí wa kò ṣe parí
- Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọlọpàá mẹ́rìn to pa afurasí, wọ́n tún dèrò ẹ̀wọ̀n
- Fayemi fojú Alufa to fipa bá ọmọde lòpọ̀ síta l'Ekiti
- Nǹkan kò ṣẹnuure fáwọn obìnrin nínú ìgbìmọ̀ ìṣèjọba Buhari
- Àwọn ọmọ Yorùbá wo ni mínísítà ní ìjọba Buhari?
- Èrò àwọn ọmọ Naijiria ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí àwọn ti Sanwo Olu yàn sípò
- Ọwọ́ ti tẹ ọlọpàá mẹ́rìn to pa afurasí
O ṣalaye pe ọgọrin lawọn afurasi ọun ti ọpọ wọn si jẹ ọmọ orilẹede Naijiria.
Hanna fikun ọrọ rẹ pe agbalagbga ti ọjọ ti lọ lori wọn lawọn eeyan yii lu ni jibiti.
Oriṣiiriṣii ẹsun to le ni ẹẹdẹgbẹta ni ajọ FBI fi kan awọn eeyan yii to to bi ọgọrin.
Ẹsun jijale owo wa lara awọn ẹsun ti wọn fi kan ọpọ Naijiria to wa lara awọn afurasi naa.








