Adebanji Akintoye fí ẹ̀yin Bola Tinubu janlẹ̀ láti jẹ́ Aṣíwáju gbogbo ilẹ̀ Yorùbá

Awọn aṣoju ẹgbẹ ọmọ Yoruba loriṣiiriṣii lo peju pesẹ sibi eto idibo ọhun.
Gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ ilẹ̀ káàrọ́ọ̀-òò jíire jakéjádò àgbáyé (Assembly of All Yoruba Groups, Worldwide) ló péjọpọ̀ ní ìlú Ibadan tíí ṣe olú ìlú Ipinlẹ̀ Oyo láti yan Aṣíwáju tuntun fún ìran Yorùbá.
Aṣiwaju yii ni yóò rọ́pò Abraham Adesanya tó ti n dari Yoruba to kú nínú oṣù kẹ́rin, ọdún 2008.
Nínú ìpéjọpọ yìí ní wọ́n ti yàn ènìyàn méjí fún ìdìbò, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu àti Ọjọgbọ́n Adebanji Stephen Akintoye.
Lẹ́yìn èyí ní àwọn ènìyàn ọkánléláadọ́rin dìbò yan Akintoye nígbà ti ènìyàn mẹ́ta yan Asiwaju Ahmed Tinubu.
Gẹ́gẹ́ bí olùgbékalẹ̀ ètò náà Victor Taiwo se sọ, ó ni Akintoye ní àwọn àmúyẹ mẹ́rìnlá ti yóò jẹ́ ki ìràn Yorùbá tẹ̀síwájú ní ọgbọ́n, ìmọ to pọ̀, ati oye.
Olori imaamu awọn musulumi Yoruba ni Ilorin, Sheik Abdulkareem Aduranigba to ṣoju fun awọn Yoruba Kwara ati Kogi lo da aba orukọ Akintoye.
Aba yii ni Ogbeni Kunle Ogundoro naa keji ki idibo to bẹrẹ laarin Tinubu ati Akintoye.
Wọn ṣapejuwe Akintoye pe ó jẹ́ olóòtọ́ sí ìtẹ́siwáju ìràn Yorubá, ó maa ń sọ ojú abẹ níkòó, ó máà ń hùwà akọni, kìí gbọ̀jẹgẹ́, ó jẹ́ ọ̀rẹ́ ará ìlú, o ni okun, ó si tún jẹ ẹni ti ìlu ń fẹ́.

Oríṣun àwòrán, Alamy
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Akintoye, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin náà kò sí nínú ìpéjọpọ òhún síbẹ̀ wọ́n dìbò yàn-án gẹ́gẹ́ bi àsíwáju tuntun fún ilẹ̀ Yoruba.
Olùgbékalẹ̀ ètò náà Victor Taiwo ní ìgbésẹ̀ náà di dandan ní àsìkò yìí nítori pé iná ìran Yorùbá tí ń jó àjórẹ̀yìn.
O ni lati igba ti adari tẹlẹ ti tẹri gbaṣọ ni iran Yoruba ko ti ki n fẹnuko mọ lati 2008.
Igbagbọ awọn to ṣeto idibo ọhun ni pé àárẹ̀ to ń mú ìràn Yorùbá yoo dopin lasiko olori tuntun yii pẹlu ìgbà ọtún to ti dé.
Taiwo ni ọpọ igba ni wọn ti kan si Alagba Ayọ Adebanjọ lati tukọ iran Yoruba ṣugbọn to kọ nitori agba ti de.
Diẹ lara awọn aṣoju ẹgbẹ to kopa ninu idibo naa ni Bodija nilu Ibadan ni: Baale Ekotedo, Oloye Taye Ayorinde; Oloye Deji Osibogun; awọn alufaaa ati imaamu aṣaaju ẹsin; ọmọ ẹgbẹ Oodua Peoples Congress (New Era).
Oodua Redemption Alliance, Majiyagbe Oodua Vanguard, Awari ọmọ Oodua, Sheik Abdulkareem Aduranigba, Olori Imam ilẹ Yoruba atawọn aṣoju lati ipinlẹ Kwara ati Kogi naa wa lara awọn to kopa nibẹ.
Awọn miran to ti jẹ olori Yoruba sẹyin ni Oloogbe Obafemi Awolowo, oloogbe Adekunle ajasin ati Oloogbe Abraham Adesanya.















