Kí ló dé tí àwọn èèyàn kan ń fi apá jánú lórí ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀yọ́?

Ọkanojọkan ariwisi ati awuyewuye lo rọ mọ eto idibo si ipo alaga ijọba ibilẹ to waye n'ipinlẹ Ọyọ lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu taa wa yii.
Saaju eto idibo naa, lasiko to n lọ lọwọ ati lẹyin rẹ ni awọn eeyan kan, paapaa julọ awọn oludibo ti ẹgbẹ oṣelu wọn yatọ si PDP to n ṣe ijọba lọwọ n'ipinlẹ Ọyọ ti n ke tantan wi pe ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, OYSIEC ṣe arumọjẹ ninu eto idibo naa, nitori awọn ohun elo fun eto idibo pẹ ki o to de si awọn ibudo idibo kan, bẹẹ sini ko tiẹ de rara si awọn ibudo mii titi ti eto idibo naa fi pari.
Ohun ti o tun mu ki ariwọ sọ ni bi ajọ OYSIEC ṣe kede lẹyin eto idibo naa pe awọn oludije lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP lo jawe olubori jakejado ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to n bẹ n'ipinlẹ Ọyọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Teslim Folarin
Folarin ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC fẹhonuhan
Lara awọn to kọkọ fi igbe ta ni oludije tẹlẹri ninu ẹgbẹ oṣelu APC si ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ ti o tun jẹ aṣoju ile igbimọ aṣofin agba, Sẹnatọ Teslim Folarin.
Fọlarin ṣe apejuwe eto idibo naa gẹgẹ bii iwa arumọjẹ ati iditẹ gba ijọba. Ninu atẹjade ti o fi ṣọwọ si awọn oniroyin nipasẹ ọkan lara awọn oluranlọwọ rẹ, YSO Ọlaniyi, o ni eto idibo ko waye ni awọn wọọdu bii ọọdunrun le laadọta jakejado ipinlẹ Ọyọ.
O tẹsiwaju wi pe "pẹlu gbogbo ileri ti ajọ eleto idibo OYSIEC ṣe lati riidaju wi pe eto idibo naa lọ ni irọwọrọsẹ lai lugọ sẹyin oludije kankan, eto idibo kọ ni ohun ti wọn ni awọn ṣe n'ipinlẹ Ọyọ lonii."
Fọlarin ni, "Ohun ti Gomina Ṣeyi Makinde ati ajọ OYSIEC fi han lonii ni arumọja lasan ti ko si jẹ itẹwọgba".
O ni Gomina Makinde ti fi han gbangba pe oun ko gbagbọ ninu iṣakoso ijọba ibilẹ, idii si niyii ti idamu fi ba idagbasoke ijọba lati ọdun marun un sẹyin.
Lara awọn eeyan ti o tun gbarata lori abajade eto idibo ijọba ibilẹ naa ni oludije tẹlẹri si ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Oyedele Hakeem lati inu ẹgbẹ oṣelu APC.
Họnọrebu to n ṣoju ẹkun idibo Ido/Ibarapa nile ile igbimọ aṣojuṣofin l'Abuja, Onimọẹrọ Remi Oseni naa fi aidun inu rẹ han lori abajade eto idibo ijọba naa.
Oseni ni iwọsi nla gbaa ni wọn fi wọ eto ijọba awa-arawa nipasẹ eto idibo to waye lọjọ Abamẹta. O gbarata lori madaru ti awọn alakoso kan ṣe nipa kiko awọn ohun elo fun eto idibo pamọ ni ẹkun idibo oun.
Oseni fi ikilọ lede wi pe ẹnikẹni ko gbudọ tẹwọ gba abajade eto idibo naa gẹgẹ bi o ṣe n rọ awọn eeyan ẹkun idibo rẹ lati kun fun adura fun ọjọ meje lati gbogun ti iwa ika ki alaafia le j'ọba.
Họnọrebu l'obinrin to n ṣoju ẹkun idibo Oluyọle nile igbimọ aṣojuṣofin, Tolulope Akande-Sadipe naa koro oju si abajade idibo naa.
Ninu atẹjade ti o fi ṣọwọ si awọn oniroyin lọjọ Aiku, Akande-Sadipe ni "awada kẹrikẹri ti wọn pe ni eto idibo ti kọja lọ, ṣugbọn mo ki awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ẹkun idibo Oluyọle ku oriire.
Iyalẹnu ni ko ba jẹ fun mi to ba jẹ pe awa a wọle, ṣugbọn esi idibo naa ko ya mi lẹnu nitori awọn alagbara to n bẹ lori ipo".
O ṣugbọn kare fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ wi pe wọn ṣe daadaa gẹgẹ bi o ṣe n parọwa si awọn to dije ninu ẹgbẹ oṣelu naa wi pe Ọlọrun nikan lo mọ awọn to jawe olubori lootọ.
O ni oun ki ajọ OYSIEC ku oriire, ṣugbọn njẹ awọn gan le fi ọwọ sọya pe ẹni to ni ade n wọn gbe ade fun?
Ẹgbẹ oṣelu 'The African Action Congress(AAC)' n'ipinlẹ Ọyọ naa ko gbẹyin ninu awọn ẹgbẹ oṣelu to fi aidun inu wọn han lori abajade eto idibo ijọba ibilẹ to waye lopin ọsẹ ti o kọja.
Ninu atẹjade ti wọn fi ṣọwọ si awọn oniroyin, ẹgbẹ oṣelu naa bẹnu atẹ lu abajade eto idibo naa, pẹlu alaye wi pe o pe ki awọn ohun elo to de ibudo idibo, awọn ohun elo kan bọ sọnu, bẹẹ sini wọn tun fi ẹsun kan wi pe ẹgbẹ oṣelu PDP lo awọn janduku lati dẹru ba awọn oludibo.
Ẹgbẹ naa tẹsiwaju wi pe abajade esi idibo naa ko jẹ itẹwọgba gẹgẹ bi wọn ṣe n ke si ajọ eleto idibo, OYSIEC lati da ọjọ tuntun ti wọn o tun ibo naa di.
Ki ni OYSIEC sọ lori eto idibo ijọba ibilẹ?
Ninu atẹjade ti o fi lede lẹyin eto idibo ọjọ Abamẹta, Hakeem ni Gomina Ṣeyi Makinde ati ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, OYSIEC tan awọn eeyan ilu jẹ nipa ṣiṣe ileri wi pe eto idibo naa yoo lọ ni irọwọrọsẹ lai tako ofin ṣugbọn idakeji ileri ti wọn ṣe ni wọn mu ṣẹ.
O pe fun atungbeyẹwo ofin ilẹ wa t'ọdun 1999 fun agbekalẹ ajọ eleto idibo ti ijọba ko ni lanfani lati tọwọ bọ, "nitori awọn to n ṣe akoso eto idibo lọwọlọwọ bayii le da oju ijọba awa-arawa bolẹ."
Ki ni ijọba ipinlẹ Oyo sọ?
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti fi ọrọ lede wi pe ijawe olubori ẹgbẹ oṣelu PDP jakejado awọn ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to n bẹ ni ipinlẹ naa ko ba awọn lojiji.
Ninu atẹjade ti wọn fi ranṣẹ si awọn oniroyin lati ọwọ Kọmisana fun iroyin, Ọmọọba Dọtun Oyelade, wọn fi idi ọrọ mulẹ wi pe awọn iṣẹ takunkun ti Gomina Ṣeyi Makinde ti gbe ṣe laarin ọdun marun un lo mu ki awọn oludije ẹgbẹ oṣelu PDP jawe olubori.
Atẹjade naa parọwa si awọn to n fi apa janu lati tẹwọgba abajade eto idibo naa, ki wọn si dẹkun lati maa da eto ijọba awa-arawa mọ ero ori lasan.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló jáwé olúborí ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ l'Ọ̀yọ́

Ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, OYSIEC ti kede abajade eto idibo si ipo alaga ijọba ibilẹ to waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2024, awọn oludije lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP lo si jawe olubori jakejado awọn ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to n bẹ n'ipinlẹ Ọyọ.
Alaga ajọ OYSIEC, Aare Isiaka Olagunju (SAN), Kọmisan ajọ Ọlọpaa n'ipinlẹ Ọyọ, Adebola Hamzat ati awọn ẹṣọ aabo ti o ku gboṣuba kare fun eto idibo naa, pẹlu alaye wi pe o lọ ni irọwọrọsẹ lai si iwa ipanle kankan bo ti n wu ko mọ.
Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) n'ipinlẹ Ọyọ ti fi ọrọ lede wi pe irọ lasan ni pe eto idibo naa lọ ni irọwọrọsẹ, nitori pe ọpọlọpọ awọn nnkan ti ko tọna ti si le da omi alaafia ilu ru lo waye ninu idibo naa
Wọnyii ni onka ibo ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi wọle ni awọn ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn naa:
1)Irepo PDP: 17,497 APC: 2,638
2) Orelope PDP: 24, 569 APC: 5,519
3) Surulere PDP: 19,493 APC: 1,619
4) Kajola PDP: 11, 232 APC: 9,373 SDP: 1,28
5) Ogo-Oluwa PDP: 9011 APC: 854 LP: 12
6) Olorunsogo PDP: 8,501 APC: 3002 NNPP: 175
7) Ido PDP: 20059 APC: 3059 LP: 498
8) Ibarapa East PDP: 13,896 APC: 1,606 SDP: 08
9) Iseyin PDP:69,896 APC: 8,241 NNPP: 581
10) Saki East PDP: 9,732 APC: 1,571 ADC:36
11) Saki West PDP: 19,621 APC: 4,920 ADC: 1,846
12) Ogbomoso South PDP: 20,102 APC: 3,471 ADC:06
13) Ibadan Northwest PDP: 21,810 APC: 3,848 ADC: 22
14) Ogbomoso North PDP: 13,681 APC: 4,691 ADC: 11
15) Akinyele PDP: 66,325 APC: 3,477 ADC: 147
16) Ibarapa Central PDP: 14,124 APC: 3,500 ADC: 14
17) Ibadan Southeast PDP: 23,220 APC: 4,265 ADC: 27
18) Atiba PDP: 19,259 APC: 5,086 ADC: 06
19) Itesiwaju PDP: 7,303 APC: 3,795
20) Atisbo PDP: 25,336 APC: 6,567 ADC: 139
21) Egbeda PDP: 24,573 APC: 5,637 ADC: 30
22) Iwajowa PDP: 5,610 APC: 2,969 ADC: 150
23) Afijio PDP: 18,662 APC: 198
24) Oyo West PDP: 12,974 APC: 3,712 ADC: 90
25) Orire PDP: 15,301 APC: 5,579 ADC: 12
26) Lagelu PDP: 65,786 APC: 4,172 ADC: 150
27) Oluyole PDP: 17,063 APC: 3,536 ADC: 55
28) Ibarapa North PDP: 17,307 APC: 6,963
29) Oyo East PDP: 27,567 APC: 3,051 ADC: 16
30) Ona-Ara PDP: 13,093 APC: 4,187 ADC: 15
31) Ibadan North: PDP - 73,240, APC - 5,548, ADC - 0
32) Ibadan Southwest: PDP - 25,702, APC - 5,978
33) Ibadan Northeast: PDP - 17,920, APC - 7,958
Kíkéde èsì ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo bẹ̀rẹ̀ padà, ayé ń retí ẹni tó wọlé

Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní ìpínẹ̀ Oyo, Oyo State Independent Electoral Commission, OYSIEC ti ní aago mẹ́sàn-án, ọjọ́ Àìkú ni ètò kíka èsì ìbò yóò bẹ̀rẹ̀.
Ní iléeṣẹ́ OYSIEC tó wà ní Agogi Gate, Ibadan ni ètò kíka èsì ìbò náà yóò ti wáyé.
Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 ni ètò ìdìbò láti yan àwọn alága àti káhúnsílọ̀ sí àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ Oyo wáyé káàkiri ìpínlẹ̀.
Bí èsì ìdìbò náà bá ṣe ń jáde ni a ó máa muwá fún-un yín.

Ètò ìbò dídì ti bẹ̀rẹ̀ káàkiri gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo láti yan àwọn aṣojú sí ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan.
Ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án òwúrò ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbgọ̀n, oṣù Kẹrin , ọdún 2024 ni ètò ìdìbò náà gbérasọ.
Ni gbọngan nla Mapo ni agbegbe Ọja'aba niluu Ibadan ni awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo, OYSIEC ti ko awọn ohun elo idibo lọ si awọn ibudo ti ibo yoo ti waye niluu Ibadan.
Aago mẹjọ owurọ lo yẹ ki eto idibo ijọba ibilẹ bẹrẹ lonii jakejado ipinlẹ Ọyọ, ṣugbọn pupọ awọn ibudo idibo ti a de ni ko bẹrẹ titi di aago mẹsan-an.
Ni bayii, eto idibo naa ti bẹrẹ ni pẹrẹu.





















