'Orí ló kó mi yọ lọ́wọ́ ikú, àwọn ọ̀rẹ́ mi mẹ́rin ni wọ́n pa'

Àkọlé fídíò,
'Orí ló kó mi yọ lọ́wọ́ ikú, àwọn ọ̀rẹ́ mi mẹ́rin ni wọ́n pa'
Ibi ti Ahmat ti ṣèṣe ní èjìká

Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin márùn-ún tí wọ́n dá dúró ní Sudan bá BBC sọ̀rọ̀ lórí ogun tó ń lọ ní Sudan.

Ahmat tó jẹ́ ẹnìkan péré tó móríbọ̀ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣàlàyé bí wọ́n ṣe dá àwọn lọ́nà tí wọ́n sì dá ẹ̀mí àọn yòókù rẹ̀ légbodò.

Ó ní ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òun pé òun móríbọ́ àti pé òun kàn farapa níbi èjìkà lásán ni.

Ó sọ pé àwọn ọ̀rẹ́ òun mẹ́rin tó kù ni wọ́n ti jáde láyé.

“A sáré dojú bolẹ̀ nígbà tí wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀.”

“Ohun tí mo rántí ni pé mò ń gbàdúrà, mo rò pé òpin ayé ti dé ni.”

Ahmat sọ pé àwọn dàbúlẹ̀ sí ibi tí àwọn dojú bolẹ̀ sí bí ẹni pé àwọn ti kú, tí òun sì fi eré ge nígbà tí òun rí àpẹẹrẹ pé wọ́n ti lọ tán.

Àwọn èèyàn tó lé ní 600,000 ni wọ́n ti sá kúrò ní ilé wọn nítorí ogun yìí.

Hatim Abdallah, olórí ikọ̀ Black Masalit ni pípa èèyàn fi jayé ni ohun tó ń wáyé ní agbègbè náà.

Abdallah ní àwọn àjọ àgbáyé nílò láti dìde sí ogun tó ń wáyé ní Sudan yìí.