A máa ṣe ìkọlù sí Iran padà – Israel fèsì

Àwọn òṣìṣẹ́ ológun Israel lásìk]o tí wọ́n ń ṣe ìpàdé

Oríṣun àwòrán, Ministry of Defence, Israel

Iléeṣẹ́ ológun orílẹ̀ èdè Israel ní àwọn máa fèsì sí ìkọlù tí Iran ṣe sí àwọn.

Olórí òṣìṣẹ́ ológun Israel, Herzi Halevi ní ìkọlù tí Iran ṣe sí orílẹ̀ èdè àwọn ní òpin ọ̀sẹ̀ kò ní lọ lásán àti pé àwọn ti ṣetán láti gbẹ̀san.

Nígbà tí Halevi ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ní Nevatim Airbase ló ṣíṣọ lójú ọ̀rọ̀ náà.

Ṣáájú ni Isreal ni àwọn ti ń wo ọ̀nà láti gbẹ̀san ìkọlù tí orílẹ̀ èdè Iran ṣe sí orílẹ̀ èdè àwọn ní òpin ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ìpè tí àwọn ń gbà káàkiri pé kí àwọn rọra ṣe láti dènà ogun tó lágbára.

Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni àwọn ikọ̀ ológun Iran tí wọ́n pe ara wọn ní Iran’s Islamic Revolutionary Guards Corps (IRGC) ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdó olóró sí orílẹ̀ èdè Israel.

Àmọ́ Isreal àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ àwọn àdó olóró náà ni àwọn kò jẹ́ kó balẹ̀.

Iran ní nítorí ìkọlù tí Israel ṣe sí dúkìá àwọn tó wà ní Syria, tí wọ́n sì pa ọ̀gá ológun àwọn ní ọjọ́ Kìíní oṣù Kérin ni àwọn ṣe ń ṣe ìkọlù yìí sí Israel.

Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tó fi mọ́ UK, US, Italy àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ Iran yìí, tí ọ̀pọ̀ wọn sì ń rọ Israel láti ṣe pẹ̀lẹ́ lórí bí wọ́n ṣe máa fèsì sí ìkọlù yìí láti dènà ogun ńlá.

Israel ní àwọn máa ṣe ìkọlù padà sí Iran nígbà tí àkókò bá tó.

Ikọ̀ ológun Israel tó ń jíròrò lórí ìkọlù náà tí àwọn kan sì ní ó yẹ kí Israel gba iná ojú Iran padà, kí àwọn náà ṣe ìkọlù tí wọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ bí wọ́n ṣe ṣe pẹ̀lú ikọ̀ Hamas nígbà tí wọ́n ṣe ìkọlù sí wọn ní ọdún tó kọjá.

Àwọn tó dúró lórí ìpinnu yìí ní èyí máa fi han Iran àtàwọn míì pé gúdúgúdú ni Israel tí kìí fi ìgbà kankan tú ara sílẹ̀ àti pé ó yẹ kí wọ́n kojú Iran bí ohun gbogbo ṣe ń gbóná báyìí.

Àwọn míì sọ pé kí Israel ṣe pẹ̀lẹ́, kí wọ́n gbọ́ gbogbo ìpè àwọn orílẹ̀ èdè tó ti ń pẹ̀tù sí wọn láti má dà á ogun mìíràn sílẹ̀ lásìkò yìí.

Wọ́n wòye pé tí Israel bá fèsì sí ìkọlù Iran lásìkò yìí máa jẹ́ ohun tó léwu púpọ̀ tó sì lè fa kí Amẹ́ríkà náà dá sí ìjà ọ̀hún.

Israel ní láti jèbùrẹ́ láti dènà ogun tó lágbára - UK

Olóòtú ìjọba UK, Rishi Sunak

Oríṣun àwòrán, PA MEDIA

Nígbà tó ń bá ilé aṣòfin sọ̀rọ̀, olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Rishi Sunak rọ Israel láti jèbùrẹ́, kí wọ́n má ṣe ìkọlù padà sí Iran.

Sunak ní òun máa bá olóòtú ìjọba Israel, Benjamin Netanyahu sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọ̀nà tí àwọn máa gbà láti ri pé ìkọlù náà kò di ìjà tó kọjá agbára.

Ó ní ìgbésẹ̀ Iran jẹ́ ojúnà láti sọ ẹkùn Middle East sínú hílàhílo àti pé ó yẹ kí àwọn wá gbogbo ọ̀nà láti dènà ohun tó le ṣokùnfà ogun ńlá ní agbègbè náà ni.

Belgium, France àti Germany wà lára àwọn orílẹ̀ èdè tó ti ránṣẹ́ pe àwọn aṣojú Iran ló rí ìkọlù tí wọ́n ṣe sí Israel.

Aworan asia orilẹ ede Iran ati Israel

Olóòtú ilẹ̀ Isrẹli, Netanyahu bá àwọn aráàlú sọ̀rọ̀

A

Oríṣun àwòrán, Reuters

Olootu ilẹ Isrẹli, Benjamin Netanyahu, ti ba awọn araalu rẹ sọrọ lori ikọlu Iran si Israel to waye lanaa.

O ni awọn ọmọ ogun Isrẹli ti gbaradi, wọn ti ṣetan labẹẹ bo ti wu ko ri tabi ohun yoowu ko ṣẹlẹ.

Netanyahu sọ pe awọn eeyan Isrẹli gan-an ti n dira ogun lati awọn ọdun diẹ sẹyin.

Koda, ni gbogbo ọsẹ meloo sẹyin pẹlu ni wọn fojoojumọ mura silẹ de ogun ti Iran le gbe ko wọn.

" Digbi ni ikọ ogun wa wa, a ti ṣetan ni gbogbo ọna. Ko baa jẹ lati gbeja ara wa tabi lati ko wọn loju.

‘’Orilẹ-ede to lagbara ni Isrẹli. Ikọ ologun Isrẹli ni ilu tiwọn. Orilẹ-ede to lagbara ni.

‘’Ohun ta n wi ko ruju, ẹnikẹni to ba koju wa, awa naa yoo koju rẹ. A maa gba ara wa silẹ lọwọ idunkooko yoowu ko fẹẹ waye, a o si ni i ṣiyemeji ‘’

Bẹẹ ni Netanyahu, Olootu ilẹ Isrẹli wi.

O dupẹ lọwọ awọn ilu to n duro ti wọn nigba gbogbo bii Amẹrika ati UK.

Ìbẹ̀rùbojo ogun gbilẹẹ̀ láwọn apá ibì kan ní Middle East

Ogun to bẹrẹ yii ko ṣẹyin ọta ti Iran pẹlu awọn alatilẹyin rẹ atawọn eeyan to n ti Isrẹli lẹyin n bara wọn ṣe.

O ti fẹrẹ pe ọsẹ meji bayii ti Iran ti n gbaradi lati fun Isrẹli lesi rẹ lẹyin ikọlu to ṣẹlẹ ni ileeṣẹ to n ri si irinajo ni Iran.

Eyi waye lọjọ kin-in-ni oṣu kẹrin ọdun yii ni Damascus.

Ikọlu Iran fi han pe wọn ti ṣetan lati gbẹsan lara Isrẹli.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Isrẹli naa ti ṣetan lati doju ija kọ ẹnikẹni to ba kọ lu u.

Ohun to waa n fa ipaya bayii fawọn ilu to wa lapa kan Middle East ni pe ija Iran ati Isrẹli le kan wọn.

Eyi ti wọn ti n dena rẹ latigba ti Hamas ti bẹrẹ ikọlu tiẹ lọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun to kọja.