Lẹ́yìn ọdún kan tí ìja Sudan bẹ̀rẹ̀

aworan

Oríṣun àwòrán, AFP

Ko yẹ ki n maa sunkun gẹgẹ bi akọroyin nigba ti mo ba n ṣiṣẹ mi lọwọ, ṣugbọn lẹnu ọjọ mẹta yii, ojoojumọ ni mo n sunkun gidigidi.

Ko too to oṣu kejila, nigba ti mo rin irin ajo lati lọ ṣe iwadii ni ibi ti mo ti wa ni Omdurman to wa ni ilu Sudanese – ibi ti ko jinna si olu-ilu, Khartoum – awọn ohun ti mo ri lati oju ferese mi ni awọn eeyan ti wọn n gbe oku awọn eeyan wọn kọpa.

Wọn n wa ẹgbẹ opopona to ṣi silẹ lati sin awọn oku naa si, nitori pe ewu nla ni yoo jẹ fun wọn, bi wọn ba gbiyanju lati lọ si itẹku.

Kini o ṣẹlẹ bayii?

Awọn araalu ti wọn ku, ọpọ wọn lo jẹ pe ọta ibọn lo ba wọn, nibi ti ija ogun naa ti bẹrẹ ni ọdun kan geerege sẹyin, nigba ti awọn agba ologun meji ni Sudan padanu ninu ọjọ iwaju oṣelu wọn, lẹyin ti wọn ti gba ijọba papọ ninu iditẹ gbajọba ti ọdun 2021.

Ọpọ awọn ọrẹ ati ibatan ni mo ti padanu

Niṣe ni ọrọ maa n di bi o ko le ki o yago lọna nigbakugba ti iro ibọn tabi bọmbu ba n dun, pẹlu ibẹrubojo ki wọn ma ṣe kagbako.

Awọn eeyan yoo sa asala fun ẹmi wọn kuro nile ara wọn, ki ikọlu naa ma ba a kan wọn.

Lọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹrin, ọdun to kọja, mo ranti daadaa pe mo fẹẹ ṣinu aawẹ Ramadaani nirọlẹ ọjọ naa ni pẹlu awọn akọroyin.

Bakan naa ni mo tun n gbaradi lati lọ pade ọrẹ mi ti a ti jọ ya ara wa lati kekere. A ko pade latigba to ti fi orileede yii silẹ.

Ara mi ko lelẹ laarọ ọjọ naa nigba ti mo bẹrẹ sii ri oriṣiriṣi lori ayelujara wi pe awọn RCF ṣe ikọlu nitosi ilu wa. Mo tun ka nipa ikọlu ni papakọ ofurufu. Mo ṣi n ro pe ikọlu naa yoo dawọ duro ni.

Ṣugbọn nigba ti ọrẹ mi kẹta kọ ọ soju opo rẹ wi pe ija nla ti bẹ silẹ ni aafi Aarẹ wa, mo ṣẹṣẹ wa mọ wi pe ogun ti de.

Nigba ti ọpọ pinnu lati kuro niluu, ẹmi ati ẹbi mi pinnu lati duro, a n ni ireti wi pe ogun naa ko ni pẹ ẹ dawọ duro, pẹlu erongba wi pe awọn orileede lagbaye yoo dide mọ wa lati pana rẹ, ṣugbọn o ṣeni laanu pe ko sẹni to ri ti wa ro rara.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn aralu ko tilẹ wa bẹru ogun to n lọ nigboro mọ, nitori pe awọn ọmọ ogun ti wọn di ihamọra gan-an n sare lọ jale lọtun ati losi. Wọn n wọle lati ko ẹru ẹlẹru lati ori mọto titi de ori ṣibi ijẹun.

Mo tiẹ ti pada si Omdurman, ṣugbọn mi o ti ni anfaani lati de ile mi. Koda mo ti gba oriṣiriṣi iroyin wi pe wọn ti yọ ilẹkun ati ferese mi, wọn si ti ko wọn lọ.

Bi ogun naa ṣe n tẹsiwaju, awọn eeyan ti n ru, wọn ti n gbẹ nitorti airi ounjẹ jẹ, ati airi omi mu. Ọja kekere to tiẹ tun wa nitosi gan-an, awọn ologun ti ṣe ikọlu sii lasiko ti wọn fẹ fọ awọn RSF danu

Awọn ile iwosan to ku ni wọn ti n tọju awọn to farapa loju ogun. Mama agba mi ku lori aisan ṣuga ti ko si ri anfaani si itọju.

Emi gan-an tun ṣaisan nitori airi ounjẹ jẹ.

Ile iwosan kereje to n ṣiṣẹ gan-an, irin ọgbọn iṣẹju ni si ibi ti mo n gbe.

Ọkan lara awọn ibatan mi lo tẹle mi lọ, iṣẹju meji-meji si ni mo n duro lọna, nitori pe mi o fi bẹẹ ni okun mọ.

Ajọ iṣọkan agbaye sọ pe ẹgbẹrun mẹwaa eeyan lo ku laarin ilu.

Gbogbo awọn eeyan ti mo n fi ọrọ wa lẹnu wo ni wọn n sọ ohun ti oju onikaluku n ri.

Ọkan mi bajẹ

Awọn orileede agbaye ni lati wa da si ogun to n ṣẹlẹ yii, ki wọn si ba awọn igun mejeeji sọrọ lati jawọ.

Ibanujẹ lo n jẹ lati maa ri ilu mi wi pe o n daru lọ, o si n fi ahoro. Pẹlu bi nnkan si ṣe n lọ yii, o ti n daju pe nnkan yoo tun buru ju bayii lọ, pẹlu bi awọn eeyan ṣe n ko ihamọra ogun sara.