Ooru tó ń mú ní Nàìjíríà ṣì máa pọ̀ síi jù báyìí lọ àyàfi... - òṣìṣẹ́ àjọ Nimet ṣàlàyé ìdí abájọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arabinrin Olumide Olaniyan, to n ṣiṣẹ pẹlu ajọ Nimet, ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ oju-ọjọ ni Naijiria ti sọ pe ooru tun maa mu sii ju bayii lọ, ‘’ti a ko ba ṣọra.’’
O ni ooru ti o n mu lẹnu ọjọ mẹta yii ni i ṣe pẹlu nnkan ti wọn n pe ni ‘’ENSO.’’
Arabinrin Olaniyan sọ pe ‘’awọn onimọ ijinlẹ sayẹnsi oju-ọjọ ti sọ ṣaaju tẹlẹ pe ti ‘El-Nino’ ba ti wa, oju-ọjọ a maa gbona.
Kii ṣe Naijiria nikan ni kini yii bawi, gbogbo agbaye ni.
Ni apa ọdọ tiwa nibi, nnkan ti o ma ṣẹlẹ ni pe ojo ko ni pọ, atẹgun to n fẹ lọsan an ati loru yoo gbona janjan.
Ti a ba sọ pe ojo ko ni pọ ko tumọ si pe ojo ko ni rọ lawọn ibomiran ti yoo fa omiyale agbara ya ṣọọbu.
Ojo yoo rọ lawọn ibikan ti yoo si fa omiyale nitori pe ‘El-Nino’ lo n ṣẹlẹ lọwọ, o ṣi maa n jẹ ki oriṣiiriṣii nnkan ṣẹlẹ kaakiri agbaye.
Ni awọn ilu miran, ojo ti o maa gbe gbogbo nnkan lọ lo maa rọ nibẹ, ṣugbọn lọdọ tiwa nibi, ojo o ni pọ bo ṣe maa n pọ to tẹlẹ.
Ohun lo jẹ ka maa ri pe ojo o ti bẹrẹ si ni fẹsẹ mulẹ kaakiri, gbogbo ibi to yẹ ko ti fẹsẹ mulẹ ninu ọdun yii.
Asọtẹlẹ awọn onimọ nipa oju-ọjọ sọ pe ooru to n mu yii, yoo mu lati oṣu Kinni titi di oṣu Karun-un.
Ojo yoo ti fidi mulẹ daadaa ninu oṣu Kẹfa, ooru a wa dinku diẹ, kii ṣe pe yoo dinku bi ti ọdun to kọja o.
Pẹlu ojo naa, ooru ṣi maa wa, ṣugbọn ko wa ni dabi bo ṣe ri bayii.
Ooru amuju yii n ṣakoba fawọn ẹranko naa, a le ma ri iran awọn ẹranko mii mọ tori oju-ọjọ to n yatọ yii.''
Arabinrin Olaniyan salaye pe ''ti omi okun Pacific ba ti n gbona ju bo ti yẹ lọ, atẹgun gbigbona lo maa maa fẹ kaakiri agbaye.
Ooru yii tun maa lagbara ju bayii lọ, ti a ba ṣi n sun igi, sun ewe atawọn nnkan mii, ara nkan to jẹ ki oju-ọjọ maa gbona niyii.''




