Ọkùnrin tí wọ́n ló lu ìyàwó rẹ̀ dójú ikú ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún BBC

Níṣe ni ìròyìn gbòde lọ́jọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Kérin ọdún 2024 pé ọkùnrin kan lu ìyàwó rẹ̀ dójú ikú ní ìpínlẹ̀ Enugu.
Ìròyìn ní Daniel Nnabuife, ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n lu ìyàwó rẹ̀ tó ń tọ́mọ lọ́wọ́ ní àlùbami tí ìyàwó náà fi jáde láyé.
Àmọ́ nígbà tí BBC News fi máa kan sí ìlú Ugboye ní Abakpa Nike, ìpínlẹ̀ Enugu níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, a bá Daniel níbi tó ti ń wa ẹkún mu bíi gààrí pé nǹkan ṣe òun.
Daniel ní ìròyìn òfégè ni pé òun lu ìyàwó òun, Blessing Nnabuife, ẹni ọdún méjìlélógún.

Daniel ní òun pàdánù ìyàwó òun sọ́wọ́ àìsàn ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà ni.
Ó ṣàlàyé pé láti ìgbà tí ìyàwó òun ti bímọ ìkókó ní nǹkan bí oṣù kan sẹ́yìn ló ti ń ṣe àárẹ̀, tí ara rẹ̀ ń wú, tí gbogbo ẹsẹ̀ rẹ̀ náà sì ń wú.
Daniel ní láti ìgbà náà ni àwọn ti ń gbe lọ sí ilé ìwòsàn kan sí èkejì ṣùgbọ́n tí àwọn kò rí ìwòsàn títí tó fi di alẹ́ ọjọ́ Ajé tí àìsàn náà tún le kóko si.
Ó fi kun pé ooru ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ìyàwó bẹ̀rẹ̀ sí ní da ẹ̀jẹ̀ lára tó sì papòdà nígbà tó máa fi di aago márùn-ún ìdájí.

Níṣe ni gbogbo ìlú Ugboye Abakpa pa lọ́lọ́, tí àwọn èèyàn sì ń dárò obìnrin tó ṣaláìsí ọ̀hún.
Ìyá olóògbé, Virginia Nwafor ní òun wá ṣe ìtọ́jú ọmọ òun tó ń ṣe àárẹ̀ àmọ́ ó ṣeni láàánú pé ọmọ òun ti papòdà.
Ẹni tó ni ilé tí wọ́n ń gbé náà, Everest Nebo ní irọ́ ni pé Daniel na ìyàwó rẹ̀ bí òun náà ṣe jẹ́rìí pé láti ìgbà tí Blessing ti bímọ láti oṣù kan sẹ́yìn ló ti ń ṣe àárẹ̀.















