Ènìyàn méjì jábọ́ sínú ọ̀sà nínú ìjàmbá ọkọ̀ lọ́jọ́ ọdún ìtúnu àwẹ̀

Ọkọ to padanu ijanu rẹ

Oríṣun àwòrán, ChannelsTV

Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá èèyàn méjì tó jábọ́ sínú odò ọ̀sà látorí afárá Third Mainland Bridge lọ́jọ́ ọdún ìtúnu àwẹ̀.

Ní nǹkan bíi aago mọ́kànlá òwúrọ̀ ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 ni ìjàmbá náà wáyé tí èèyàn bá ti fẹ́ ẹ̀ dé ìyànà Adeniji.

Ìjánu ọkọ̀ ni a gbọ́ pé ó fa ìjàmbá ọkọ̀ náà.

Àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì náà ní àwọn òṣìṣẹ́ ààbò inú omi ti ń wá àwọn tí wọ́n jàbọ̀ sínú odò náà.

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn mìíràn tó farapa ló ti wà ní ilé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

Ibi ti ijamba naa ti waye

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ẹṣọ oju popo to n mojuto ọna

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn ẹṣọ oju omi to n wa awọn to ko sinu odo ọsa

Oríṣun àwòrán, NEMA

Adarí ètò àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, Olatunde Akinsanya tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ọkọ̀ èrò náà pàdánù ìjánu ọkọ̀ rẹ̀ lórí eré.

Akinsanya ní bí dírẹ́bà ṣe pàdánù ìjánu ọkọ̀ náà ló lọ forí sọ igun afárá náà táọn èèyàn méjì sì fò jábọ́ sínú odò.

Ó ní àwọn ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú omi àti àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ti ìjọba àpapọ̀, ìyẹn NEMA láti ṣàwárí àwọn tó jábọ́ sínú odò ọ̀sà náà.

Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ààbò ló wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti ri pé wọ́n ṣàwárí àwọn èèyàn ọ̀hún.

Ẹ ó rántí pé ní ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹrin ni ìjọba àpapọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí afárá Third Mainland lẹ́yìn ṣíṣe àtúnṣe tó gbòòrò níbẹ̀.