A kábàmọ́ọ̀ pé a dìbò fún Ààrẹ Bola Tinubu - ẹgbẹ àgbààgbà apá àríwá Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Ahmed Bola Tinubu/X
Ẹgbẹ agbaagba apa ariwa orilẹede Naijiria, Nothern Elders Forum (NEF) ti sọ pe awọn kabamọọ wi pe awọn dibo fun Aarẹ Bola Tinubu ninu eto idibo aarẹ ti o gbe e wọle lọdun 2023.
Ninu awọn oludije fun ipo aarẹ mẹta to lewaju ninu ibo aarẹ Naijiria ọdun 2023, Tinubu ti i ṣe oludije ẹgbẹ APC lo ri ibo to pọ julọ.
Agbẹnusọ ẹgbẹ NEF, Abdul-Azeez Suleiman, ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu iwe iroyin Guardian, sọ pe ẹkun ariwa yoo jiroro daadaa lori ẹni ti wọn yoo dibo fun un gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria lọjọ iwaju.
Suleiman ni oludije ti gbogbo eeyan fọwọ si ti ko ni ṣegbe lẹyin ẹnikan tabi omiran lawọn yoo dibo fun gẹgẹ bi aarẹ Naijiria lọjọ iwaju.
‘’Ẹkun ariwa ṣe aṣiṣe nipa bi wọn ṣe dibo fun Tinubu ninu ibo aarẹ ọdun 2023, a o ni ṣe iru aṣiṣe bayii mọ lọjọ iwaju.
A ti kẹkọọ ninu aṣiṣe ati igbesẹ wa bayii, a o ṣi yan ẹni ti yoo so Naijiria pọ ati ẹni to ni ifẹ araalu lọkan sipo lọkan lọjọ iwaju.
Ni bayii, ẹkun ariwa yoo ṣora ṣe ti wọn ba fẹ yan aarẹ Naijiria lọjọ iwaju.
Aṣiṣe ibo ti a di fun Tinubu lọdun 2023 ti kọ wa lẹkọọ iṣepataki iṣokan ati fifẹnuko lori oludije ti a o dibo fun gẹgẹ bi aarẹ,’’ Suleiman lo sọ bẹẹ.
Ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu Aarẹ Tinubu pẹlu bi gbogbo nnkan ti gbowo lori ni Naijiria.
Ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, to ṣikeji ninu ibo aarẹ ọdun 2023 sọ pe ọpọ eto ti ijọba Tinubu gunle ni ko ṣenu ire fun araalu.
Atiku sọrọ yii lẹyin ti ijọba kede afikun owo ina mọnamọna.
Ẹwẹ, aarẹ ti n fi dawọn ọmọ Naijiria loju pe gbogbo nnkan n bọ wa dẹrọ laipẹ.















