Portale olórin jẹ ẹ̀bùn mọ́tò, nítorí Bobrisky tó kọrin bú

Bi akọrin Zazu, Habeeb Okikiọla (Portable) ṣe sare wọ ile orin to si po orin pọ tako Bobrisky, ọkunrin to n ṣe bii obinrin, ti fun un lanfaanni mọto ayọkẹlẹ Benz bayii.
Funra Portable lo sọ eyi di mimọ lasiko to wa loko ere kan pẹlu Ẹniọla Ajao, oṣerebinrin to ṣe sinima Ajakaju to da awuyewuye silẹ laipẹ yii.
Portable ti wọn tun n pe ni Idaamu adugbo, sọ pe, ‘’Nitori Ẹniọla Ajao ni. Fiimu rẹ, Ajakaju, da wahala silẹ, emi dẹ gba mọto Benz nitori mo sọ wahala naa d’orin.’’
Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an?

Oríṣun àwòrán, Eniola Ajao@Instagram
Ẹniọla Ajao lo ṣafihan sinima rẹ to si pe Bobrisky (Idris Okunẹyẹ Ọlanrewaju) sibẹ.
Nibi eto naa ni wọn ti ni Bobrisky ni imura rẹ gba ipo kin-in-ni ninu awọn obinrin to wa lode naa.
Eyi lo di wahala, to dohun ti awọn oṣere bii Dayọ Amusa ati Fẹmi Adebayọ n sọko ọrọ sira wọn lori ayelujara.
Bakan naa lọpọ eeyan koro oju si bi wọn ṣe fun Bob to jẹ ọkunrin lami-ẹyẹ obinrin, nigba ti awọn eleto naa mọ pe akọ to n mura bii obinrin ni.
Ẹniọla Ajao to ni ere ọhun paapaa kabaamọ pe oun fun Bobrisky lami ẹyẹ ati miliọnu kan naira to tẹle ami-ẹyẹ naa.
O sunkun lori ayelujara, o si tọrọ aforiji lọwọ awọn eeyan.
Bi wahala naa ṣe n lọ lọwọ ni Bobrsisky naa n sọ pe awọn obinrin ko rọgbọn ẹ da, afi ki wọn gba oun saarin wọn.
O loun ti ṣe idi, oun ṣe ọyan, oun si ti yọ nnkan ọkunrin kuro labẹ oun, ti obinrin lo wa nibẹ bayii.
Inu bi Portable, o kọrin ’ẹ lẹ ẹ loko pa ’ fun Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky222@Instagram














