Ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re ní kí Tinubu dá owó iná mọ̀nàmọ́ná padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀

Aworan ẹgbẹ Afẹnifẹre ati Aarẹ Bọla Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/ Bọla Tinubu

Ẹgbẹ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Yoruba ni Naijiria, Afẹnifẹre, ti koro oju si afikun owo ina ti ijọba Aarẹ Bọla Tinubu ṣe faraalu lọsẹ to kọja yii.

Wọn ni ki Aarẹ da owo naa pada si bo ṣe wa tẹlẹ.

Atẹjade kan ti Afẹnifẹre fi sita lọjọ Satide, ọjọ Kẹfa oṣu kẹrin 2024 yii, eyi ti agbẹnusọ wọn, Jare Ajayi, buwọ lu lo sọ eyi di mimọ.

Afẹnifẹre ṣalaye pe ileeṣẹ apinnaka, Nigerian Electricity Distribution Company (NERC) n fi aikunju oṣuwọn tiwọn ni awọn eeyan Naijiria lara pẹlu afikun naa.

‘Aráàlú ló ń jìyà ‘sọbsidi’ tíjọba yọ lórí epo, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò rí fún ti iná mọ̀nàmọ́ná’

Aworan Aarẹ Bọla Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale

Afẹnifẹre ṣalaye pe nigba tijọba yọ owọ iranwọ rẹ kuro lori owo epo, araalu ti ko mọwọ-mẹsẹ lo n jiya rẹ bayii.

"Araalu to fẹẹ lo ohun tawọn to n sanwo gọbọi lori ina ba ṣe ni yoo jiya afikun owo ina yii, gẹgẹ bo ṣe ri lorii sọbsidi epo tijọba yọ.

‘’Awọn ileeṣẹ yoo fowo kun ohun ti wọn ba n pese sita, awọn eeyan to fẹẹ ra ni inira yoo si ba.

‘’ Ina ti araalu o ri lo tẹ ẹ tun n fowo kun. NERC kan fẹẹ k’awọn eeyan Naijiria maa jiya aikunju oṣuwọn ileeṣẹ tiwọn ni.

‘’ Kaka ki wọn ronu ọna mi-in ti wọn le fi din owo ti wọn fi n pese ina ku, wọn ro pe kawọn kuku ṣafikun owo faraalu lo daa.

‘’Awọn eeyan tẹ ẹ ro pe afikun yii kan nikan kọ ni yoo koju inira rẹ, ilọpọ marun-un ọmọ Naijiria to n lo ohun ti wọn n pese ni.

Kì Tinubu pàṣẹ fún iléeṣẹ́ tó ń rí sí iná mọ̀nàmọ́ná láti dá àfikún owó yìí dúró, kí wọ́n ronú ọ̀nà ìpèsè mí-ìn bíi solar ati ìjì

Lakootan,Afẹnifẹre ni ki Aarẹ Tinubu tete paṣẹ fun ileeṣẹ to n ri si ọrọ ina ọba ninu ijọba rẹ, ki wọn gbagbe afikun ọhun patapata.

Wọn ni aile ronu ọna abayọ mi-in lati ṣẹgun iṣoro ni wọn ṣe gbe ilana inira kalẹ fawọn eeyan Naijiria.

Ẹgbẹ naa sọ pe k’awọn onina ronu ọna tuntun tina le gba wa lai mu inawo pupọ danu fun ileeṣẹ wọn.

Awọn bii solar, iji (wind) ati afẹfẹ (gas).

‘’ Ironu ati iṣẹ iwadii awọn kan la fi n gbọ FM redio lonii, Short wave lo wa laye atijọ.

‘’Asiko kan lawọn eeyan n lo kọmputa nla lorii tabili, alagbeeka wa bayii to ṣee gbe kiri.

‘’K’awọn naa ronu ọna ti wọn le gba yanju iṣoro ileeṣẹ wọn, ki wọn ma fi tiwọn ko ba mẹkunnu Naijiria’’

Bayii ni Afẹnifẹre wi ninu atẹjade wọn.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú

Tẹ o ba gbagbe, Ọjọru, ọjọ Kẹrin oṣu kẹrin ni NERC kede lorukọ ijọba apapọ, pe afikun to le ni ida igba yoo ba owo ina awọn onibaara to wa ni isọri A.

Awọn to wa ni ipin yii ni wọn sọ pe wọn n lo ina fun ogun wakati tabi ju bẹẹ lọ lojumọ.

Wọn ni afikun naa ki i ṣe fun awọn yooku ti wọn ko si ni ipin yii, eyi to fi jẹ pe iwọnba perete lawọn to kan.

NERC ṣalaye pe awọn onibaara naa yoo maa rina lo ju ti tẹlẹ lọ.

Awọn yoo maa pese rẹ, wọn ko si ni i kowo nla ra disu abi epo eyikeyi mọ.

Ṣugbọn latigba ti ikede naa ti jade lawọn eeyan ti n koro oju si i, wọn ni ko sẹni to n rina lo fun ogun wakati.

Ọpọlọpọ lawọn ko tié mọ pe isọri ina tun wa.

Wọn ni arumọjẹ ati ọna lati ni awọn lara ni awọn onina ọba n ṣe.