Àgbẹ̀ tó ń gbin igbó rí ẹ̀wọ̀n he ní Ibadan

Awon osise NDLEA ninu oko igbo naa

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ile ẹjọ giga ijọba apapọ to n bẹ niluu Ibadan ti sọ agbẹ ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Arakunrin Monday Ode si ẹwọn ọdun mẹfa gbako lori ẹsun pe o n gbin egbogi oloro ti iwọn rẹ to kilo mọkanlelaadọta.

Adajọ Ekerete Akpan gbe idajọ rẹ kalẹ nipase ẹri aridaju ti ajọ to n gbogun ti lilo egbogi oloro, NDLEA fi han ati bi afurasi naa ṣe jẹwọ wi pe lootọ ni oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Adajọ naa ni ọwọ aanu wa ninu idajọ ti oun ṣe nitori igba akọkọ niyii ti afurasi naa yoo dan iru nnkan bẹẹ wo.

Ile ejo giga ipinle Oyo to wa ni Ibadan
Awon osise NDLEA ninu oko igbo naa

Oríṣun àwòrán, NDLEA

O kilo fun Arakunrin Ode lati dẹkun iru iwa bẹẹ lẹyin ti o ba ti ẹwọn de, nitori o ṣeeṣe ki o fi ẹwọn gbere jura bi wọn ba tun pada gbaa mu lẹẹkeji.

Saaju ni gbẹjọro fun ajọ NDLEA, O.O. Olorunsola sọ fun ile ẹjọ pe ẹsun meji otọọtọ ni wọn fi kan afurasi naa. Akọkọ ni pe o n pin igbo, ẹlẹẹkeji ni pe o n taa.

Olorunsola fi kun ọrọ rẹ wi pe lọjọ kejila oṣu kẹsan an ọdun 2023 ni kele ofin gbe Arakunrin Ode ni agbegbe Apata niluu Ibadan.

O ni ajọ NDLEA gbe igbesẹ naa lẹyin ti awọn olugbe agbegbe ọhun ta wọn ni olobo wi pe Arakunrin Ode ti o jẹ ọmọ ipinlẹ Benue ti sọ ilẹ kan di ibi to n gbi kilo mọkanlelaadọta igbo si. Lori ilẹ naa si ni kele ofin ti gbee.