Akẹ́kọ̀ọ́ KWASU mẹ́fà rí ẹ́wọ̀n he ní Ilorin lẹ́yìn tí wọ́n jẹ̀bi ẹ̀sùn ṣíṣe Yahoo

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria, EFCC, ti ẹkun Ilọrin ti ri idajọ gba nile ẹjọ bi ile ẹjọ ṣe ju akẹkọọ mẹfa ṣẹwọn.
Awọn akekọọ naa ni wọn kawọ pọn rojọ niwaju adajọ Evelyn Anyadike ti ile ẹjọ giga to wa ni Ilọrin, olu ilu ipinlẹ Kwara.
Awọn akekọọ na ni, Aransiola Oluwaseun Stephen lati ijọba ibilẹ Okeẹro ni Kwara, Owoẹyẹ Adeyanju lati Ibadan, ati Idris Kayọde lati ipinlẹ Eko.
Awọn to ku ni Abdulrahmon Abubakar lati Surulere, ipinlẹ Oyo, Rafiu Ashimiu ati Raheem Ayọmide tawọn mejeji wa lati Ilọrin, ni ipinlẹ Kwara.
Pẹlu idajọ yii, o ti di awọn akekọọ mẹrinlelogun ti ile ẹjọ ju ṣẹwọn ninu aadọta awọn akekọọ ile ẹkọ giga fasiti ijọba ipinlẹ Kwara, KWASU ti EFCC mu fẹsun iwa ibajẹ ori ayelujara.
Lasiko igbẹjọ naa, awọn agbẹjọro ajọ EFCC, Innocent Mbachie, Adebayọ Aliu, Charles Oni ati Rasheedat Alao sọ fun ile ẹjọ pe awọn ẹri maa jẹ mi nṣo to wa nilẹ fi han pe wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọ.
EFCC sọ siwaju si pe awọn ohun ti wọn gba lọwọ awọn afurasi naa pẹlu ibi ti wọn ti mu wọn safihan ẹri ti wọn ni nile ẹjọ.
Lẹyin ọrọ awọn agbẹjọro adajọ ile ẹjọ ju wọn ṣẹwọn.
Adajọ tun pasẹ ki wọn padanu gbogbo ẹrọ ibanisọrọ ti wọn n lo fi sisẹ laabi naa ati ẹrọ kọmputa alagbeka, to fi mọ pẹlu owo ti wọn gba lọwọ awọn ti wọn lu ni jibiti sọwọ ijọba apapọ.
Adajọ ni awọn akẹkọọ ọhun n jẹ orukọ mii lori ẹrọ ayelujara ti wọn si n lu awọn oyinbo ni jibiti owo dọla.
Ṣaaju lọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji ọdun 2024 yii ni ajọ EFCC mu awọn akẹkọọ KWASU naa ti iye wọn to aadọta fẹsun jibiti ori ẹrọ ayelujara.














