Ooru àmújù gbẹ̀mí èèyàn ní South Sudan, ìjọba gbé gbogbo ilé ẹ̀kọ́ tìpa

Oríṣun àwòrán, Paula Bronstein
Ijọba South Sudan ti paṣe ki wọn ti gbogbo ile ẹkọ pa bayii latari ooru amuju ti wọn ni yoo kọlu orilẹ-ede naa laipẹ.
Awọn alaṣẹ ilẹ naa ni ki gbogbo ọmọde wa ninu ile, ki awọn obi wọn si bojuto wọn nitori ooru naa le mu fun ọsẹ meji gbako.
Awọn onimọ sọ pe ooru ọhun ti mimu rẹ le to ‘113 degrees Fahrenheit’ le ṣakoba fun eeyan.
Iroyin ni awọn eeyan kan ti ku nibẹ bayii laari ooru amuju ọhun.
Ṣaaju ni awọn eeyan to n gbe niluu Juba, to jẹ olu ilu ilẹ naa ti kọkọ n pariwo ooru latari bi ooru amuju naa ṣe ge ina ẹlẹtiriki.
Gẹgẹ bii nnkan ti ẹka banki agbaye to n mojuto ooru sọ, kii ṣe akoko yii lo yẹ ki irufẹ ooru bẹẹ mu.
Aworan lati Juba ṣafihan awọn ọmọ ile ẹkọ ti wọn n pada sile wọn lọjọ Aje lẹyin ti awọn alaṣẹ ile ẹkọ wọn da wọn pada.
Ṣaaju ni ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ, eto ilera ati ọrọ ayika ti kọkọ sọ pe awọn yoo gbe ile ẹkọ ti pa lọjọ Aje nitori akoba ti ooru naa ṣe fun awọn akẹkọọ.
Wayi o, awọn ileeṣẹ ijọba naa ko sọ ni pato asiko ti wọn yoo ṣi awọn ile ẹkọ pada.
Amọ ṣa, awọn olukọ kan ti sọ fun BBC pe wọn yoo ṣi ile ẹkọ awọn pada lọjọ kẹta, oṣu Kẹrin.
Awọn ile iwosan kan sọ fun BBC pe iye alaisan ti wọn ti gba wọle ti pọ ju ti tẹlẹ lọ lẹyin ti ooru naa bẹrẹ.
Ọdun 2011 ni South Sudan gbominira lọwọ orilẹ-ede Sudan, eyii to mu ko jẹ orilẹ-ede ti ọjọ ori rẹ kere julọ lagbaye.














