Àwọn òṣìṣẹ́ fásitì SSANU àti NASU bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ méje káàkiri Naijiria

Aworan SSANU/ NASU

Iyanṣẹlodi ọlọjọ meje ti bẹrẹ bayii lati ọdọ awọn oṣiṣẹ fasiti ti wọn ki i ṣe olukọ, SSANU àti NASU kaakiri Naijiria.

Ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 ni SSANU àti NASU bẹrẹ iyanṣẹlodi ọhun latari owo oṣu mẹrin ti wọn ni ijọba apapọ jẹ awọn.

Awọn ti iyanṣẹlodi yii kan ninu ọgba fasiti ni awọn to n gbowo wọle, awọn olugbaniwọle, awọn aṣọ́gbà, awọn to n bojuto atunṣe ohun eelo to ba bajẹ, awọn to n ri si ọrọ awọn akẹkọọ ati bẹẹ bẹeẹ lọ.

Ọdun 2021 ni ijọba apapọ bẹrẹ ofin ‘ko siṣẹ ko sowo’ fawọn oṣiṣẹ fasiti, lẹyin iyanṣẹlodi oloṣu rẹpẹtẹ to waye nigba naa.

Ṣugbọn loṣu keji ọdun 2024 yii, ijọba san owo oṣu mẹrin ajẹsilẹ fawọn ASUU, wọn ko fun SSANU ati NASU rara, eyi to fa a tawọn eeyan naa fi lawọn yoo yanṣẹ lodi.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ kede iyanṣẹlodi yii pẹlu alaye pe ijọba apapọ fi awọn gun lagidi, pẹlu bi wọn ṣe sanwo oṣu mẹrin fun ASUU ti wọn ko si san tawọn.

Bi yoo ṣe wa niyẹn fọjọ meje, afi bijọba ba sanwo tiwa naa- Aarẹ SSANU

Aarẹ SSANU, Mohammed Ibrahim, ṣalaye laarọ ọjọ Aje pe iyanṣẹlodi yii yoo maa tẹsiwaju bẹẹ fọjọ meje, afi bijọba ba sanwo tawọn naa nikan.

O fi kun un pe bijọba ba kọ lati ṣẹtọ lẹyin ọjọ meje iyanṣẹlodi ikilọ yii, awọn yoo tun gbe igbesẹ to ba yẹ ni.

Aarẹ SSANU tẹsiwaju pe akẹkọọ nikan kọ ni iṣoro yii yoo kan, o ni gbogbo eeyan to ba ni nnkan lati ṣe ni yunifasiti ni yoo foriko o.

Ibrahim sọ pe nitori ko ni i sina, ko ni i somi tabi ohun amayedẹrun kankan.

Bakan naa lo koro oju si bijọba ṣe n pin awọn oṣiṣẹ fasiti si ọtọọtọ, ti wọn n sanwo apa kan gbagbe apa keji.

O ni eyi ko yẹ bẹẹ rara.

Ibrahim lawọn ti fi ẹhonu awọn to ijọba leti tẹlẹ, wọn ko kọbi ara si i ni, bẹẹ ni wọn ko fesi pada bawọn ṣe kọwe ifisun si wọn to.

Àwíjàre ìjọba àpapọ̀

Minisita eto ẹkọ ni Naijiria, Ọjọgbọn Tahir Mamman, sọ fun ileesẹ iroyin Punch pe oun ko gbọ nipa iyanṣẹlodi awọn SSANU/NASU.

Ninu atẹjiṣẹ ti minista naa fi ranṣẹ si akọroyin Punch lo ti ni oun ko gbọ pe iyanṣẹlodi kankan fẹẹ waye.

O ni ṣugbọn oun mọ pe iṣẹ ti bẹrẹ lori ọrọ naa lẹka ijọba to ga julọ.