A mọ ọ̀nà àbáyọ sí ètò àbò tó mẹ́hẹ ní Nàìjíríà, tí ìjọba bá fẹ́ gbọ́- Ẹgbẹ́ Fulani Kullen-Allah

Oríṣun àwòrán, Other
Ẹgbẹ Fulani darandan Kullen-Allah ti sọ pe awọn mọ ọna abayọ si iṣoro eto abo to n koju orilẹede Naijiria lọwọ yii.
Ẹgbẹ Kullen-Allah fidi ọrọ yii mulẹ lẹyin ipade wọn to waye niluu Maiduguri, ipinlẹ Borno lopin ọsẹ to lọ.
Adari ẹgbẹ naa, Họnọrebu Khalil Muhammad Bello sọ fun BBC wi pe awọn pe ipade ọhun lati jiroro lori bi alaafia yoo ṣe jọba laarin awọn agbẹ atawọn darandaran ati kaakiri orilẹede Naijiria.
Họnọrebu Bello ṣalaye pe awọn tun jiroro lori bawọn eeyan ko ṣe ni maa ṣe ifọhonuhan mọ eyi ti wọn gbagbọ pe o n ṣakoba nla fun orilẹede Naijiria.
Bakan naa ni ẹgbẹ Kullen-Allah tun ke si gbogbo awọn darandaran ni Naijiria pe ki wọn yago fun ohunkohun to ba le ṣakoba fun eto abo.
‘’Ti ijọba apapọ ba ṣetan lati gbọ, a mọ ojutuu si iṣoro eto abo to n koju Naijiria lọwọ yii, eyi ti ko tiẹ ni na ijọba lowo rara bi eto Fulako,’’ Họnọrebu Bello lo sọ bẹẹ.
Ti ẹ o ba gbagbe, Aarẹ Bola Tinubu ti buwọlu eto kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni ‘Fulako’ eyi ti ijọba yoo pese ilegbe tuntun, ile iwosan, ile ẹkọ to fi mọ ile itọju awọn ẹranko gẹgẹ bi ọna lati wa ojutuu si iṣoro awọn janduku agbebọn atawọn ajinigbe to n yọ awọn eeyan apa ariwa Naijiria lẹnu.
Ẹgbẹ Kullen-Allah ni iṣoro eto abo yoo di ohun igbagbe laarin oṣu meji pere, ti ijọba ba le tẹle imọran awọn.
Ẹya Fulani jẹ ẹya kan ti ọpọ n fi ẹsun kan wi pe awọn lo n da omi alaafia Naijiria ru papaa julọ lapa ariwa Naijiria.
Ọpọ gbagbọ pe awọn ni wọn n ji awọn eeyan gbe ti wọn n gba owo nla fun itusilẹ wọn, ti wọn ko si tun jẹ kawọn agbẹ le lọ si oko mọ.















