Gbogbo àwọn tó ṣekúpa ọmọ ogun 16 ní Delta ni yóò jìyà lábẹ́ òfin – Ìjọba

Nigeria Army

Oríṣun àwòrán, getty images

Ijọba ipinlẹ Delta ti koro oju si iṣekupani awọn ọmọ ogun Naijiria to waye ni ilu Okuama, ni ijọba ibilẹ ila oorun Ugheli.

Gomina ipinlẹ naa, Sheriff Oborevwori sọ pe ijọba oun yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ lati ṣawari gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu awọn jagunjagun naa, wọn yoo so foju wina ofin.

Oborevwori lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Fewstus Ahon fi lede.

Gomina ọhun wa ba mọlẹbi awọn ologun to ba iṣẹlẹ naa lọ kẹdun.

O ni iṣẹlẹ naa burui jai, o si jẹ ohun ajeji si awọn eeyan ipinlẹ Delta lati maa pa awọn ologun to n daabo bo ilu.

Bi ọrọ naa ṣẹ bẹrẹ

Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ migboro titi nipa bawọn ọdọ kan ṣe kọlu awọn ologun ti iye wọn jẹ mẹrindinlogun.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria fi lede, o ni awọn kan lo ke pe ileeṣẹ ọmọ ogun lati da si aawọ kan niluu Okuoma amọ ti awọn ọdọ kan ṣekupa awọn ologun to lọ sibẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, Tukur Gusau sọ ninu atẹjade naa pe adari ikọ awọn ologun to lọ sibẹ, ọgagun mẹta to ni oye ‘Major’ ati ‘Captain’ to fi mọ ọmọ mejila lo ba ikọlu naa lọ.

Gusau sọ pe awọn ọdọ ilu naa kọ lati jẹ ki awọn akẹgbẹ awọn ologun naa ti wọn ke pe wọ ilu ọhun lati doola wọn.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ija kan to waye laarin ilu Okuama ati Okoloba lawọn ologun ti wọn pa naa n lọ yanju ki wọn to pade iku ojiji lọwọ awọn ọdọ ilu ọhun.

Ẹwẹ, ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, ọgagun Gwabin Musa ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ iwadii ni kankan lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣokunfa akọlu naa.

O si ti fi ọrọ to ijọba ipinlẹ Delta leti.

Ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori ikọlu awọn ọmọ ogun naa ati iku wọn.

Ti pupọ ninu araalu si n bu ẹnu atẹ ikọlu ọhun.