Wo bí arábìnrin kan ṣe fi WhatsApp gbà ọ̀pọ̀ obìnrin lóko ẹrú ọmọ-ọ̀dọ̀ ní Oman

Georgina to de lati Oman
    • Author, By Florence Phiri in Lilongwe & Tamasin Ford in London
    • Role, BBC Africa Eye

BBC Africa Eye ṣe iwadii bi arabinrin kan ṣe lo WhatsApp lati doola awọn obinrin Malawi to le ni aadọta loko ẹru ọmọ ọdọ lorilẹede Oman.

Ikilọ: Awọn nnkan mii to wa ninu iroyin yii le bawọn eeyan kan ninu jẹ.

Obinrin ọmọ ọdun mejilelọgbọn bu sẹkun nigba to ranti ohun ti oju rẹ ri nibi to ti lọ ṣe ọmọ ọdọ lorilẹede Oman.

Georgina, to lo orukọ kan gẹgẹ bi gbogbo awọn to ba BBC sọrọ ṣe loo, ṣalaye pe iṣẹ awakọ loun ro pe oun n lọ ṣe ni Dubai gẹgẹ bi ohun ti wọn sọ fun oun.

Georgina n ṣe owo kekeke ni Lilongwe tii ṣe olu ilu orilẹede Malawi, nigba ti ẹnikan sọ fun un pe yoo ri owo gidi to ba le lọ ṣiṣẹ ni ẹkun Middle East.

Nigba to de si ilu Muscat tii ṣe olu ilu orilẹede Oman ni o mọ pe wọn ti tan oun wa si Oman ni nibi to bi bẹrẹ si ni ṣiṣẹ aṣekara fun ọjọ meje laarin ọsẹ.

O ni nigba ti o di aarin kan ẹmi oun ko gbe mọ lẹyin ti oun bẹrẹ si ni fi wakati meji pere sun.

Ko tii pẹ ti Georgina de Omar ti ọga rẹ fi fẹ maa ba a ni ibalopọ ti o si sọ fun un wi pe oun maa yinbọn fun un ti ko ba gba.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‘’Oun nikan kọ lo maa n fipa ba mi sun, o tun maa n ko awọn ọrẹ rẹ naa wa nigba mii ti wọn yoo si sanwo fun un ti wọn ba ti ṣetan.’’

Ohun Georgina n gbọn lati ṣalaye bi wọn ṣe bẹrẹ si ni ba ni ibalopọ lati ile iyagbẹ.

‘’Mo ṣeeṣe gan an, inu mi si bajẹ.’’

Akọsilẹ fihan pe bi miliọnu meji obinrin lo n ṣe ọmọ ọdọ nilẹ Araabu.

Iwadii ajọ De Bold to n ri si to ri si ọrọ awọn aṣatipo to lo irinwo obinrin sọ pe o fẹ jẹpe gbogbo awọn obinrin yii ni wọn fi ṣe kata-kara.

Bii idakan ninu idamẹta wọn lo sọ pe wọn fipa bawọn lopọ, nigba ti idaji ni wọn huwa ipa ati idẹyẹsi sawọn.

Lẹyin ọsẹ diẹ, gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ti toju su Georgina, o si beere iranwọ lọwọ ẹnikan lori Facebook.

Pililani Mombe Nyoni ọmọ Malawi to jẹ alẹnulọrọ ori ayelujara to wa ni ipinlẹ New Hampshire lorilẹede America lo ri ọrọ ti Georgina kọ sori Facebook fun iranwọ, o si bẹrẹ si ni iwadii ọrọ naa.

Bayii ni Nyoni ṣe kan si Georgina ti o si yọ ẹbẹ Georgina kuro lori Facebook lati daabo bo o.

Nyoni fi nọmba WhatsApp rẹ ranṣẹ si Georgina, eyi ti ọpọ eeyan bi ti Georgina pada ni lorilẹede Oman.

Nigba naa ni o wa ri pe iṣoro nla ni ọrọ naa ni Oman.

‘’Georgina lo kọkọ fara kaaṣa, lẹyin naa lo kan ọmọbinrin kan, o tun wa kan ọmọbinrin meji.

Nigba naa ni mo pinu lati ṣe agbekalẹ ẹgbẹ kan lori WhatsApp niyẹn,’’ o ṣalaye fun BBC.

Awọn ọmọbinrin Malawi to le ni aadọta to wa loko ẹru ọmọ ọdọ ni Oman lo darapọ mọ WhatsApp ti mo ṣe agbekalẹ rẹ.

Bayii ni ọpọ ninu bẹrẹ si ni fi oriṣiiriṣii ohun ati fidio ranṣẹ sori ikanni WhatsApp yii eyi to lagbara gan an.

Ọpọ ninu wọn lawọn ọga wọn gba iwe igbelu wọn lọwọ wọn ki wọn maa ba lanfani ati kuro.

Ọpọ ninu wọn ṣalaye bi wọn ti lọ fi ohun ranṣẹ nile iyagbẹ lati ṣalaye iya to n jẹ wọn.

‘’Ṣe lo dabi ẹni pe inu ẹwọn ni mo wa...a o le rọna salọ laelae.’’

Ẹnikan ni ninu wọn sọ pe ‘’inu ewu ni mo wa.’’

Bayii ni Nyoni bẹrẹ si ni bawọn ajọ to n gbogun ti fifi eeyan ṣe kata-kara ni Malawi sọrọ.

Nigba naa ni o mọ Ekaterina Porras Sivolobova, to jẹ oludasilẹ ajọ Do Bold to wa ni orilẹede Greece.

Ajọ De Bold n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn aṣatipo to n ṣiṣẹ lawọn orilẹede Araabu.

Igbesẹ akọkọ ni lati mọ awọn eeyan ti wọn fi ṣe kata-kara tabi ti wọn n fi ṣe ẹru, lẹyin naa ni wọn o ba ọga wọn sọrọ lori ati tu wọn silẹ.

‘’Awọn olugbaniṣiṣẹ maa n sanwo fawọn oṣiṣẹ abẹle tabi aṣoju lati bawọn wa ọmọ-ọdọ to le ṣiṣẹ.

Ara awọn ipenija ti a maa n koju ni pe awọn ọga to ti sanwo fun ọmọ-ọdọ yii maa n beere owo wọn pada ki wọn to gba pe ki wọn maa lọ,’’ Arabinrin Sivolobova lo sọ bẹẹ fun BBC.

‘’Ofin orilẹede Oman ko faye gba ọmọ-ọdọ lati fi ọga rẹ silẹ.

Ọmọ-ọdọ o le paarọ iṣẹ, ko si le fi orilẹede naa silẹ, ohun ti kii baajẹ pe o n ṣẹlẹ si i.’’

Ohun ti wọn n pe ni iṣẹ Kafala niyi lẹkun Middle East, eyi to tumọ si pe oṣiṣẹ ko le fi ọga rẹ silẹ titi ti adehun iṣẹ rẹ yoo fi pari.

Igbimọ to n gbogun ti fifi eeyan kata-kara lorilẹede Oman ni adehun lo wa laarin ọga ati ọmọ-ọdọ, ati pe ileẹjọ lo le pari ọrọ tabi ija to ba ṣẹlẹ laarin awọn mejeeji.

Igbimọ naa sọ pe ọga ko laṣẹ lati fi ọmọ-ọdọ to gba ṣe ẹru tabi fi iwe igbelu rẹ pamọ lai gba aṣẹ lọwọ ọmọ-ọdọ naa.

Lẹyin to ti lo oṣu mẹta ni Muscat, Georgina pada si Malawi lọdun 2021 pẹlu iranlọwọ arabinrin Nyoni ati ẹnikan lorilẹede Oman.

Nyoni sọ pe ‘’inu bi mi gidi gan lẹyin ti o ṣe iranwọ fun Georgina tan.’’

Ọpọ eeyan ni Malawi lo gbọ ohun to ṣẹlẹ si Georgina,eyi to si jẹ ki ijọba bẹrẹ si kọminu lori ọrọ naa.

Ajọ CDEDI to n ri si ọrọ ijọba awarawa ati idagbasoke ọrọ-aje ṣe ifilọlẹ ipolongo didoola awọn obinrin Malawi to wa loko ẹru.

Blessings jẹ obinrin mii to wa ninu ẹgbẹ WhatsApp ti Nyoni ṣe agbatẹru rẹ.

Ọdun 2022 ni Blessings, ẹni ọdun mọkandinlogoji rinrin ajo lọ si ilu Muscat, ti o si fi ọmọ rẹ mẹrin ṣọ aunti rẹ, Stevelia, to wa ni Lilongwe.

O tiẹ fara jona gan an ni ile idana ọga rẹ, amọ, iyẹn o sọ pe ki ọga rẹ gba a laye lati pada si Malawi.

‘’Ina to jo Blessings pọ gan an, koda , mo ri i bi ẹni ti ẹmi ti fẹ bọ lara rẹ ni.

Mo ranti pe Blessings sọ fun mi pe oun lọ si Oman lati ṣiṣẹ owo ni, ṣe ẹmi oun ko ni bọ bayii.

Lẹyi naa lo sọ pe ki n ba oun tọju awọn ọmọ oun. Ọrọ naa ba mi lọkan jẹ,’’ Stevelia ṣalaye.

Stevelia ati Blessings miMalawi
Àkọlé àwòrán, Blessings ri awọn ẹbi rẹ pada ni Malawi

Stevelia bẹrẹ lati maa wa ọna ti Blessings yoo fi pada wale.

Nigba to ya, awọn aṣoju to n gbe awọn ọmọ-ọdọ lọ si Oman sọ pe Blessings ti ku.

Amọ, irọ ni tori Blessings pada si Malawi loṣu Kẹwaa ọdun to lọ pẹlu iranwọ ijọba Malawi.

‘’Mi o tiẹ lero wi pe mo tun maa ri ẹbi mi atawọn ọmọ mi mọ.

Mi o mọ tẹlẹ pe awọn eeyan kan wa ti wọn maa n lo awọn ọmọ ọdọ bi ẹru,’’ Blessing lo sọ fun BBC bẹẹ.

Ijọba Malawi to ṣiṣẹ pọ pẹlu Do Bold sọ pe oun na $160,000 lati doola awọn obinrin ọmọ Malawi mẹrinlelaadọta wale lati Oman.

Ṣugbọn posi ni wọn fi gbe Aida Chiwalo pada wa si Malwi ni tiẹ, koda, wọn o le ṣe ayẹwo ohun to ṣekupa a ni Oman.

Ijọba Oman ni ko si ẹni to mu ẹjọ kankan to ni ṣe pẹlu ọmọ-ọdọ lati Malawi wa lọdun 2022.

Arabinrin Sivolobova sọ pe ọpọ awọn obinrin Malawi yii gba itusilẹ tori awọn ọga wọn ti gba owo wọn pada, owo bii $1,000 si $2,000 ni wọn gba ki wọn to jẹ ki wọn kuro.

Sivolobova sọ pe ‘’ohun to n kọ mi lominu ni pe wọn ni lati fi owo ra ominira wọn ni.’’

Agbẹnusọ fun ijọba Malawi ni ijọba n ṣiṣẹ lori ofin ti yoo maa daabo bawọn to n ṣatipo kaakiri.

Georgina leti odo Lake Malawi
Àkọlé àwòrán, Georgina leti odo Lake Malawi

Arabinrin Nyoni to ṣe agbekalẹ ẹgbẹ kan lori WhatsApp lati maa sẹ iranwọ fawọn obinrin ti wọn fi ṣe kata-kara si Oman ni iṣoro awọn obinrin Malawi to ha si orilẹede Oman n ṣafihan oṣi ati airiṣẹṣe to wa ni Malawi.

‘’Tawọn omọbinrin ba ri iṣẹ ṣe ni Malawi ni, wọn o ni lọ ha si Oman.

A ni lati tun orilẹede yii ṣe ki a le dẹkun bi awọn ọdọbinrin ṣe n lọ ha silẹ ajeji.’’

Georgina ṣi n ro nipa ohun ti oju rẹ ri ni Oman. O maa n saba lọ si eti odo Lake Malawi ti yoo si maa wo o ki ara rẹ le balẹ.

‘’Nigba kugba ti mo ba wo bi omi yii ṣe n ru ni mo maa n ranti pe ko si ohun to ni ibẹrẹ ti ko lopin.

Gbogbo rẹ yoo pada di itan lọjọ kan.

Ọkan mi ti n balẹ, mo ṣi maa n gba ara mi ni iyanju pe mo maa pada si bi mo ti wa tẹlẹ,’’ Georgina lo sọ bẹẹ.