Oṣù mẹ́fà nínú ọdún ni mo fi ń ṣiṣẹ́ l’Amẹrika, owó rẹ̀ ni mo fi ń tún ìlú ṣe - Onidera
Onidera ti ilu Idera, Ọba James Oladipo Buremoh ti ṣalaye bo ṣe maa n lo oṣu mẹfa nilẹ Amẹrika ti yoo si pada wa fi owo to ba pa lọhun tun ilu to jọba le lori ṣe.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba ni Onidera, to ti fi akoko igba kan jẹ onijakadi lọpọ ọdun sẹyin ṣalaye ọrọ naa.
Irawọ Onidera tan kaakiri gbogbo agbaye lọdun 1987 lasiko to gba ade ijakadi lẹyin to na akẹgbẹ rẹ Mike Hayes lori papa.

Oríṣun àwòrán, Onidera
Orukọ ti wọn mọ ọ si lọdun naa lọhun ni ‘Ladi the African Tiger.’
Lẹyin to fẹyinti gẹgẹ bii ajijakadi lo bẹrẹ iṣẹ awakọ niluu New York, nilẹ Amẹrika.
Bo tilẹ jẹ pe oun ni abikẹyin iya rẹ, baba rẹ sọ fun ṣaaju iku rẹ pe oun ni yoo jẹ ọba ilu Idera lẹyin ti ọba to wa lori oye ba gbesẹ.
“Mo sọ fun ilu pe oṣu mẹfa ni maa lo lati fi ṣiṣẹ l’Amẹrika”
Ori ade naa ṣalaye fun BBC pe nigba ti ọba to wa lori alefa ilu Idera gbesẹ ti oye si kan oun, oun tọwọ bọwe adehun pẹlu ilu Idera pe oṣu mẹfa ni oun yoo maa lo nilẹ Amẹrika lati ṣiṣẹ ti oun yoo si lo oṣu mẹfa to ku ninu ọdun lori itẹ Idera.
O ni “Mo sọ fun wọn pe... Ẹ fun mi laaye ki n maa lo oṣu mẹfa ni ilu Oyinbo, ki n maa lo oṣu mẹfa nile, ah, wọn ni awọn gba.
“Nitori ẹni to ba loun joko pe o daa mo ti jẹ ọba mo wa fẹ kẹkẹ nisin ebi o pa ṣege si ẹni ọhun lara, nitori bẹẹ ni mo ṣe lọ.

Oríṣun àwòrán, Onidera
“Awọn bọọsi gbọọrọgbọọrọ ti wọn fi n gbe awọn arinrinajo afẹ kiri ‘New York sightseeing’ ni mo n wa nigbayẹn ni New York.”
Kabiesẹi ni owo ti oun ba pa nidi iṣẹ awakọ l’Amẹrika naa loun fi n tọju awọn ọmọ oun, owo naa si loun fi n tun ilu Idera ṣe.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ araalu ni ko faramọ pe odidi ọba alaye n ṣiṣẹ awakọ niluu oyinbo, Onidera ko pa iṣẹ naa ti, osi maa n lọ ṣiṣẹ l’Amẹrika lati ṣiṣe fun itẹsiwaju idile ati ilu rẹ titi di oni.
Onidera pari ọrọ rẹ pe oun kii ṣe ọba to maa n paṣẹ fun eeyan ti iṣẹ ba delẹ, oun maa lọwọ si awọn iṣẹ ti bo n lọ niluu.
Yatọ si owo ti Onidera n gbe kalẹ fun itẹsiwaju ilu rẹ, o tun maa n ni ajọṣepọ ijọba loorekoore.
Ẹkunrẹrẹ ohun ti Onidera ba wa sọ wa ninu fidio oke yii.















