Inflation: NBS ní ìpínlẹ̀ Kogi, Delta àti Kwara wà lára ìpínlẹ̀ tí oúnjẹ ti léwó

Eroja Ounjẹ

Oríṣun àwòrán, @HygiNnadi

Ajọ to n ṣe iṣiro idagbasoke fun ijọba apapọ lorilẹede Naijiria, NBS ti pariwo sita pe, awọn ohun jijẹ ati mimu bayii ti di ọwọngogo.

Ninu agbejade iwadi iṣiro rẹ lori bi owo ori awọn ohun jijẹ ati mimu ṣe lọ si loṣu kẹjọ si ikẹsan ọdun yii.

Ajọ NBS ni, ida mọkanla o le diẹ ninu ọgọrun (11.24%) ni ohun jijẹ tun fi gbowo lori sii laarin oṣu kẹjọ si ikẹsan.

Lati oṣu kẹjọ, ti ijọba apapọ ti ti awọn ẹnu ibode orilẹede Naijiria pa, ni awọn owo ori ohun jijẹ lorilẹede Naijiria ti gbe ẹnu soke, lẹyin to ti wa silẹ fun awọn saa diẹ.

Sọọbu itaja kan pẹlu ọlọja ibẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi ohun ti ajọ NBS gbe jade, ipinlẹ Kogi ni ounjẹ ti wọn julọ, lẹyin naa ni ipinlẹ Delta pẹlu Kwara. Bakan naa lo ni ipinlẹ Kano ati Zamfara ni owo ori ohun jijẹ ti fara rọ julọ fun oṣu kẹsan.