APC Oyo: Àkọsílẹ̀ rere wà pé Ajimobi ni gómìnà tó dáńtọ́ jùlọ ní Ọyọ

Oríṣun àwòrán, @OfficialSeyiMakinde
Igun ọdọ ninu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ọyọ ti nahun kesi gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde lati sisẹ tọ awọn ogun isejọba to da lori ilana onidagbasoke ti asaaju rẹ, Abiọla Ajimọbi fi lelẹ nipinlẹ Ọyọ.
Alakoso igun ọdọ kan ti wọn n pe ni OFI, Ọgbẹni Ayọ Adekanmbi lo gbe imọran yii kalẹ ninu atẹjade kan to fisita nilu Ibadan eyi to da lori bijọba Seyi Makinde se fẹ gba owoya biliọnu meje ati aabọ naira.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bakan naa ni Adekanmbi tun rọ ijọba to n tukọ ipinlẹ Ọyọ lọwọlọwọ lati gbajumọ eto isejọba pẹlu gbogbo aayan to yẹ, nitori ni ilẹ toni to mọ yii, ijọba Ajimọbi nikan lo tayọ gẹgẹ bii ijọba to duro re ti yoo tukọ ipinlẹ Ọyọ lati ọdun 1976.

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimobi
"Akoko to taa sọ ootọ ọrọ pọnbele fun gomina Seyi Makinde pe ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun ni iwa to rawọ le lati fẹ pa oju ẹsẹ asaaju rẹ, Abiọla Ajimọbi rẹ ninu itan akọọlẹ rere nipinlẹ Ọyọ, nitori ijọba Ajimọbi lo tii pegede julọ lati ọdun 1976 ti wọn ti da ipinlẹ Ọyọ silẹ."
- Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò kó tó jọba
- Yatọ̀ fún orí ìtàgé, wo ohun tí o kò mọ̀ nípà Mr Latin
- 'Ọwọ́ wa tún tẹ ojúkòó tí wọ́n tí ń bá àwọn ọmọdékùnrin lò pọ̀ ní Daura'
- Ṣé lónìí ni ọ̀rọ̀ owó oṣù tuntun yóò yanjú àbí yóò tún d'ọjọ́ míràn?
- Ìrọ̀rùn dé l'Ekiti! A óò bẹ̀rẹ̀ sí san 30,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù lóṣù yìí- Fayemi
Adekanmbi tẹsiwaju pe, o ti wa ni akọsilẹ pe Ajimọbi gbaradi ko to gba akoso ipinlẹ Ọyọ lọdun 2011, to si fi ipilẹ rere lelẹ nipa mimu idagbasoke ba awọn ohun amayedẹrun.








