Minimum Wage: Àlékún owó náà leè má pọ̀, àmọ́ yóò ju ₦30,000 lọ

Oríṣun àwòrán, Ijoba ipinle Eko
Gomina ipinlẹ Eko Babajide Sanwo-Olu ti ṣeleri lati san ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira lọ fawọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa.
O sọ ọrọ yii lẹyin ipade kan to ṣe pẹlu awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ lọjọ Iṣẹgun.
Nibi ipade naa, Sanwo-Olu ni kete ti ijọba apapọ ati awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ba ti pari ọrọ lori ẹkunwo yii, ni ijọba ipinlẹ Eko yoo bẹrẹ si ni san an.
Gomina naa ni oun fẹ san ju ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira lọ nitori pe awọn mọ riri ohun ti oju awọn oṣiṣẹ n ri lọjojumọ.
''O le ma pọ ṣugbọn a o san ju ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira ẹkunwo oṣu''
O tẹsiwaju pe '' A mọ pe awọn eeyan n fi oju ipinlẹ nla wo ipinlẹ Eko,a si mọ ohun ti oju awn oṣiṣẹ n ri l'Eko bakanna.Ti awọn ipinl miran ba le san iye yi, mo nigbagbọ pe o yẹ ki ijba Eko ṣafihan imoore sawọn oṣiṣẹ ti wọn ṣiṣẹ tọ idagbasoke Eko''

Oríṣun àwòrán, Alamy











