A ti ra ọkọ̀ akérò BRT tí yóò rọ́pò àwọn ọkọ̀ dáńfó l'EKo - Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ni eto ti wa nilẹ lati fopin si sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ nipinlẹ naa.
Sanwo-Olu lo sọ ọrọ yii ni apejọpọ kan ti akọle rẹ n jẹ "The Platform" ti ijọ Convenant Christian Centre ṣagbekalẹ rẹ.
Gomina ọhun ni ojo to gbode kan lo mu ki awọn iṣẹ akansẹ oju ọna ma a falẹ lọwọ yii.
O ni o wu oun lati ṣe awọn oju opona to ti bajẹ ni ipinlẹ Eko, sugbọn o ṣoro lati fi ọjọ kan bọ ọmọ to ba ru yo.
Gomina naa mẹnuba diẹ lara awọn ohun to lero pe o n fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ni ipinlẹ naa bi, opopona ti ko dara, ojo arọrọda ati bi awọn eeyan ṣe pọ lapọju.
Sanwo-Olu sọ pe o le ni ogun miliọnu awọn eeyan to n gbe n'ipinlẹ Eko, to si yẹ ki ipinlẹ naa ti ni ibudokọ ọkọ oju irin toba ode oni mu.

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu
O wa sọ siwaju si pe, eto ti wa nilẹ lati sisẹ lori ọkọ oju irin ti yoo ma na agbegbe Mile 2 si Marina.
Sanwo-Olu pari ọrọ rẹ pe ijọba rẹ ti ra ọkọ akero BRT to le ni ẹgbẹta eyi ti yoo rọpo awọn ọkọ akero 'Danfo' to wa ni igboro.













