IAAF World Championships: Abiyamọ kan di lobìnrin tó leè sáré "100 meters" jùlọ l'àgbáyé

Oríṣun àwòrán, @BBCSport
Obinrin ọmọ ọdun mejilelogun kan lati orilẹ-ede Jamaica ti wọ inu iwe itan gẹgẹ bi obinrin to lee sare ori papa oniwọn ẹsẹ ọgọrun un julọ l'agbaye.
Shelly-Ann Fraser-Pryce to jẹ ọlọmọ kan tun ni ẹni to dagba ju l'gbaye to gba ife ẹyẹ naa lẹyin to gba ife wura ni idije agbaye to n lọ lọwọ ni Doha, lorilẹ-ede Qatar.
Dalemoṣu yii lo sa ere ori papa naa larin iṣẹju mẹwaa o le diẹ, lati gba ife ẹlẹẹkẹjọ iru rẹ ti yoo gba.
Lẹyin to gba ife ẹyẹ naa tan, o ni inu oun dun gidigidi.
O ṣalaye siwaju sii pe, aṣiri aṣeyọri oun ni iwa irẹlẹ ti oun ni ati bi oun ṣe mu iṣẹ oun lokunkundun.
Bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ awọn ololufe ere ori papa ni ko yọju lati wo Shelly-Ann ni igba to n sa ere naa, o ni oun ko bikita rara.
Ṣaaju akoko yii ni Shelly-Ann ti kopa ninu awọn idije agbaye miran bii; idije Olympic ti Beijin lọdun 2008, idije agbaye Berlin lọdun 2009, idije Olympic ti Londo lọdun 2012, ati bẹẹbẹẹ lọ.









