#StopRobbingUs: Ilé-isẹ́ ọlọ́pàá Naijiria gbọdọ̀ jáwọ́ nínú ìfìyajẹni

Olopaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọjọ́ 29, ní Osu Kẹ̀sán ni àwọn òsìsẹ́ onimọ̀ ẹ̀rọ parapọ̀ sọ wí pè òtógé pẹ̀lú bíí àwọn ọlọ́pàá se ń fìyàjẹwọ́n ní ọ̀na àìtọ́.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn eniyan jankan-jankan ni ẹka imọ ẹrọ lorilẹ-ede Naijiria ti da owo jọ pọ lati gbe ile isẹ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria lọ si ile ẹjọ lori ẹsun pe wọn n fi iya jẹ wọn lọna aitọ.

#StopRobbingUs ni wọn n lo lati fi fi ẹhọnu wọn han lori ẹrọ ayelujara lori bi awọn ọlọpaa se n na wọn, ti wọn si n gba owo ni ọwọ wọn lọna aitọ.

Olopaa

Oríṣun àwòrán, OTHER

Àkọlé àwòrán, Wọn si ti ri owo to to miliọnu mọkanla Naira($30,000) ni aarin ọjọ kan.

Lati Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Kẹsan an, ni wọn bẹrẹ si ni ko owo naa jọ, ti wọn si ti ri owo to to miliọnu mọkanla Naira ($30,000) ni aarin ọjọ kan.

Àkọlé fídíò, Intersextuality: Dokita ni ká mu èyì tó wù wá nínú jíjẹ́ akọ tàbí abo

Ọkan lara awọn to n fẹhọnu han naa sọ bi ọrọ naa se bẹre pẹlu bi ajọ ileesẹ ọlọpaa ṣe bẹrẹ, bakan naa ni awọn miran si bẹrẹ si ni fi fidio bi awọn ọlọpaa se fi iya jẹ wọn lede.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Awọn to wa ni idi ifẹhọnu han naa wa kesi ijọba orilẹ-ede Naijiria ko tọwọ awọn ọlọpaa Naijiria bọsọ, nitori awọn ṣetan lati taatan pẹlu wọn.

Àkọlé fídíò, Nigeria Independence Day: Sé ẹ mọ̀ pé ọdún 1956 ló yẹ́ ká ti dòmìnira ṣùgbọ́n....

Awọn eniyan yii ni wọn ni ẹri to pọ to n ṣafihan bi awọn agbofinro Naijiria ṣe maa n huwa aitọ si awọn eniyan nibikibi.

Gbogbo eniyan ni wọn n pe ni ọmọ Yahoo ti awọn ọlọpaa si n foju ole wo.

Titi di asiko yii, awọn agbofinro ko tii sọ nkankan lori awọn #StopRobbingUs ṣugbọn awọn eniyan agbegbe naa ni ajọ to n mojuto ẹsun awọn ara ilu ti bẹrẹ iwadii to yẹ.

CRU

Oríṣun àwòrán, @Police_CRU

Iroyin ni ileeṣẹ ọlọpaa ti mu awọn oniṣẹ ibi kan ni agbegbe H Command ni Ogudu to gba owo lọwọ ninu awọn to n kọminu yii.

Àkọlé fídíò, Olojo festival: Fídíò bí èrò ṣe darapọ̀ mọ́ Ọọ̀ni láti ṣọdún Ọlọ́jọ́ nílé Ifẹ̀ nìyí