Ọwó ọlọpàá tẹ adigunjalè márun un àti babaláwo tó ń ṣògùn fún wọn ni Imo

Ibi nkan Amuṣagbara awọn ole naa

Oríṣun àwòrán, Facebook

Àkọlé àwòrán, Ojubọ Babalawo

Ọwọ ajọ ọlọpaa ti tẹ babalawo kan ati awọn adigunjale marun ni Ipinlẹ Imo.

Meji ninu awọn afunrasi naa ni wọn fara kaṣa ọta ibọn awọn Ọlọpaa, ti wọn si farapa ki ọwọ to ba wọn.

Nigba ti ajọ ọlọpaa n fi oju awọn ọdaran naa lede, Kọmiṣọna fun awọn Olọpaa ipinlẹ ọhun, Rabiu Ladodo ṣe afihan orukọ awọn ọdaran bii.

Ikenna Eze ti wọn mọ si Fela, ẹni ọdun mẹtalelogun, Harrison Okorafor ti wọn tun pe ni Doctor, ọmọ ọdun mọkanlelogun, Eze Emeka, ọmọ ọdun mẹtalelọgbọn, ati awọn miran.

Ladodo sọ pe, Ogubuike to jẹ Ogboju Ọlọṣa to ti n yọ awọn eniyan agbegbe gbungbun ati Ariwa Ideato lẹnu ni ọwọ tun tẹ.

O tẹsiwaju pe, ọjọ kẹrin Oṣu kẹsan Ọdun yii ni ọwọ palamba rẹ segi, ni dede agogo meji ọsan, ni agbegbe Rock View ti Ọga Ọlọpaa Banjoko Wẹmimọ n dari.

Ipinle Imo

Oríṣun àwòrán, others

Ladodo ni, ogboju Ole naa jẹwọ ẹsun idigunjale ti wọn fi kan.

Ṣe ni ọjọ kọkanla ọsu kẹsan ọdun yi ni afurasi naa ti mu awọn Olọpaa lọ si ibi ikọkọ ti awọn ọdaran akẹgbẹ rẹ to ku wa, ni ibi ti olori awọn ọdaran naa, Ikenna Eze ati Chukwu Ezeala fi ara pamọ si.

Oga Ọlọpaa ṣalaye pe, ni ṣe ni awọn ọdaran naa n rọ ojo ibọn lemọlemọ pẹlu ọlọpaa, ti Chukwudi Ezeala ati Ikenna Eze si fara pa.

Lẹyin eyi ni ọwọ tẹ babalawo kan ti orukọ rẹ n jẹ Eze Emeka ni Enugu.

Awọn Ọlọpaa wi pe oriṣiriṣi nkan ija oloro ni wọn ba nibi ojubọ babalawo yi, to si jẹwọ pe lootọ ni ohun n ṣe iṣẹ laabi.

Àkọlé fídíò, Olojo festival: Fídíò bí èrò ṣe darapọ̀ mọ́ Ọọ̀ni láti ṣọdún Ọlọ́jọ́ nílé Ifẹ̀ nìyí