Revolution Now: Ilé ẹjọ́ dá Omoyele Sowore padà sí àhámọ́ DSS

Oríṣun àwòrán, @Tony_Nwajei
Ile ẹjọ giga to wa l'Abuja ti da Omoyele Sowore pada si ahamọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, titi di igba ti ile ejọ ọhun yoo tẹti si ipẹjọ beeli rẹ.
Sowore ti wa ni ahamọ lati ọjọ kẹta oṣu kẹjọ ọdun yii, lẹyin ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ fi panpẹ ọba mu ni ilu Eko.
Ile ẹjọ ni ko pada si ahamọ titi di ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrin, oṣu kẹwaa fun akọtun ibeere
Ile ẹjọ kan ti kọkọ da a silẹ, sugbọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ orilẹ-ede yii kọ lati tu silẹ.
Ṣaaju ni ijọba apapọ ti fi ẹsun to ni ṣe pẹlu fifi ipa gba ijọba kan oun ati ẹnikeji rẹ, Olawale Bakare, ti awọn memeji si ni awọn ko jẹbi ẹsun naa.
Amofin agba Olumide Fusika, to jẹ agbẹjporo fun Sowore rọ ile ẹjọ na lati tu silẹ lẹyin ti wọn ti wọn gba beeli rẹ lọsẹ to kọja.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Sugbọn adajọ to n gbẹsun naa, Ijeoma Ojukwu kọ lati da Sowore ati ojugba rẹ Bakare silẹ.
Lẹyin naa ni adajọ ọhun paṣẹ pe ki wọn da awọn memeji pada si ahamọ DSS titi di ọjọ Ẹti, ti yoo fi gbọ ẹjọ beeli awọn olujẹjọ ọhun.
Omoyele Sowore tí dé ilé ẹjọ́ ní Abuja!
Omoyele Sowore tí dé ilé ẹjọ́ ní Abuja!
Omoyele Sowore ti wa ni ile ẹjọ lẹyin ti ijọba orilẹ-ede Naijiria gbe e lọ si ile ẹjọ lori ẹsun pe ile ẹjọ ko lasẹ lati da Sowore silẹ.
O ti wa ni ile ẹjọ ba yii, ti gbogbo eto si ti to lati gbo ẹsun ati idi ti ijọba fi kọ lati tu u silẹ, lẹyin ti ile ẹjọ pasẹ ki wọn tui silẹ.À ń dúró de ìwé ìrìnnà Sowore kí a tó fisílẹ̀ - DSS
Aago mẹsan an kọja iṣẹju mẹẹdogun ni Omoyele sowore de sile ẹjọ ni abuja ṣaaju Adajo Ijeoma Ojukwu ti n gbọ ẹjọ ọhun.
Ẹsun meje ni awọn ajọ DSS fi kan Sowore bayii bii eyi ti wọn ni o bu aarẹ Buhari lori itakun agbaye, kiko owo jade lọna aitọ ati iditẹgbajọba.

Oríṣun àwòrán, @vickisex
Sowore ati Olawole Bakare ti wọn n pe ni Mandate ni wọn jọ gbe wa sile ẹjọ laarọ yii.
Awọn mejeeji si ti ni awọn ko jẹbi awọn ẹsun yii rara.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Omoyele Sowore ti pari gbogbo eto beeli rẹ lọjọru ṣugbọn awọn alaṣẹ kọ lati tu u silẹ.
Lọjọ Iṣẹgun ni ile ẹjọ paṣẹ ki awọn ọtẹlẹmuyẹ tu agbatẹru iwọde Revolution Now ti wọn fi si ahamọ lori ẹsun pe o fẹ fiditẹgbajọba silẹ.












