Nigeria at 59: Nàiajíríà ni olú ìlú àwọn tó tòṣì jùlọ làgbáyé - Atiku

Oríṣun àwòrán, @atiku
Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbe PDP, Alhajai Atiku Abubakar ti ni, bi orilẹ-ede Naijiria ti n ṣe ajọyọ ọdun mọkandinlọgọta to gba ominira, nnkan le koko fun awọn ọmọ orilẹ-ede yii.
Atiku lo fi ọọ naa lede loju opo Twitter rẹ nigba to n sọrọ lori awọn kudiẹkudiẹ ti orilẹ-ede yii n dojukọ.
O ni "Nnkan ko rọgbọ bi orillẹ-ede yi ṣe jẹ olu ilu awọn to toṣi julọ lagbaye, bẹẹ naa ni ọpọlọpọ awọn ọmọde to yẹ ko wa ni ileewe n fẹsẹ gbalẹ kiri."
Atiku ṣalaye siwaju sii pe "Awọn oniroyin ko lee sọrọ bo ti tọ ati boti yẹ lai bẹru pe awọn alagbara kan yoo fiya jẹwọn."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Igbakeji aarẹ ana ọhun ni, bo tilẹ jẹ pe Naijiria n dojukjọ ọpọlọpọ iṣoro, ọla yoo dara fun orilẹ-ede yi.
Atiku wa gbadura fun Naijiria, lẹyin naa lo tun pe gbogbo ọmọ Naijiria lati gbagbọ pe Naijiria yoo dara.
Nigeria at 59: Osinbajọ ní Ọlọrun ti ṣèlérí Nàìjíríà tuntun, TUC ní Nàìjíríà ti kùnà

Oríṣun àwòrán, Instagram/Osinbajo
Naijiria yoo pe ọmọ ọdun mọkandinlọgọta ni ọla!
Ṣaaju ọjọ Iṣẹgun ti orilẹ-ede Naijiria yoo pe ọdun mọkandinlgọta to di ilẹ olominira, igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Oṣinbajo ati Aarẹ ologun tẹlẹ ri, ajagun fẹyinti Yakubu Gowon ti sọ pe ireti si wa pe nnkan yoo ṣẹnu 're fun Naijiria.
Osinbajo ati Gowon sọrọ yii nibi ijọsin to waye lọjọ Aiku fun ayajọ ominira orilẹ-ede Naijiria niluu Abuja.
Igbakeji Aarẹ ṣalaye nibi isin naa pe Ọlọrun ti ṣetan lati mu orilẹ-ede Naijiria de ilẹ ileri.
Ọjọgbọn Oṣinbajọ ṣalaye siwaju sii pe Eleduwa lo n ṣakoso ohun gbogbo, Oun naa si lo n dari ayanmọ orilẹ-ede gbogbo atawọn eeyan to wa nibẹ.
Igbakeji aarẹ ni ''Eleduwa ti ṣetan lati fun wa ni Naijiria tuntun nibi tawọn ọmọ Naijiria yoo ti rọwọ họri, ati nibi ti iṣokan yoo ti wa laarin ẹlẹyamẹya gbogbo.''
Bakan naa nibi ijọsin ọhun, ajagun fẹyinti Gowon rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ Naijiria lati yago fun iwa to le da wahala lorilẹede Naijiria.
Gowon ni oun gbagbọ pe Ọlọrun to ti n da Naijiria si lati igba ominira si wa sibẹ lati maa daabo boo, ṣugbọn awọn ọmọ Naijiria gbọdọ kun fun adura.
Ṣugbọn ọrọ ohun dabi ilu gangan an to jẹ pe ohun to kọju sẹnikan, ẹyin lo kọ sẹlominran.
Lẹyin ti ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC sọ pe ipo ti Naijiria wa lawujọ awọn orilẹ-ede fihan pe Naijiria ti kuna lati dagbasoke lẹyin to ti gba ominira fọdun mejidinlọgọta.
Aarẹ ẹgbẹ TUC, Quadri Olaleye ṣalaye pe iwa ajẹbanu, awọn ologun to sọ ara wọn di oloṣelu, ija ẹlẹyemẹya ati ẹleṣinmẹsin wa lara awọn ohun to n gbogun ti idasoke Naijiria.
Awọn lọkan-o-jọkan naa lo ti n sọrọ pe ojọ iwaju Naijiria si maa dara lẹyin ọdun mọkandinlọgọta to ti gba ominira.
Ọjọ kinni, oṣu kewaa, ọdun 1960 ni orilẹ-ede gba ominira lọwọ ilẹ Gẹeṣi to koo lẹru.












