Minimum Wage: A i sí ìlànà owó sisan ló n dá àfikún owó oṣù òṣìṣẹ́, dúró- NLC

Oríṣun àwòrán, others
Lẹyin bi wakati meloo kan ti ijọba apapọ kede p'awọn ti san ẹkunwo ọgbọn Naira owo oṣu oṣiṣẹ Naijiria, awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ kan lawọn ko ti i ri apẹrẹ rẹ lọdọ awọn.
BBC fi ọrọ wa ninu awọn tọrọ kan lẹnu wo bii Comrade Ambali Akeem to jẹ alaga ana ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Ogun.
Comrade Ambali ni owo yii ko le di sisan lawọn ipinlẹ nitori pe ẹnu awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ijọba apapọ ko tii ko lori ilana sisan owo naa.
O ni ọgbọn arekereke ni ijọba apapọ n lo ati pe niṣe ni ''wọn n gbe ẹsin siwaju kẹkẹ lori ọrọ naa''.
Comrade Ambali ni: 'Ijọba apapọ lawọn ti san owo yi fawọn oṣiṣẹ to wa ni ipele ikini titi de ipele kẹfa, bawo leyi ṣe le ṣeeṣe nigba ti ko si oṣiṣẹ kankan to wa ni ipele ikini?''
Ambali ni bi ẹgbẹ oṣiṣẹ ko ba ri ilana owo sisan yi bo ti ṣe kaari awọn oṣiṣẹ, ko le rọrun ki ijọba ipinlẹ tabi ti ibilẹ kankan san owo afinkun owo oṣu yi.
Aṣoju awọn oṣiṣẹ yii ni ọna abayọ si ọrọ yii ni ki ijọba ṣe ohun to yẹ lasiko.
O mẹnuba owo ori awọn ounjẹ ati ohun eelo to ti gbowo lori gọbọi lasiko yii pe owo oṣu awọn oṣiṣẹ ko too naa rara.













