Minimum Wage: Alága òṣìṣẹ́ Ekiti ní òǹyẹ̀ kò leè yẹ sísan ₦30,000 owó oṣù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alága ẹgbẹ́ òṣìsẹ́ ìpínlẹ̀ Ekiti, Kolapọ Olatunde ti kéde pé ,ìjọba àpapọ yóò san ẹgbẹ̀rún lọna ọgbọn náírà owó oṣù òṣìsẹ́ tó kére jùlọ losù kẹ́sàn ọdún yìí.
Olatunde sàlàyé èyí nílu Ado -Ekiti, lásikò tó fi n dá àwọn àkọroyin lójú pé, kò sí ǹkan tó le yẹ aigbowó osù fáwọ́n òṣìṣẹ́ nínú ọ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́ nínú òṣù tọ ń bọ̀ yìí.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn ọmọ Nàíjíríà ló ṣiṣẹ́ takò mí ní Ireland kí ń má baà wọlé ìbò Káńsélọ̀ - Yemi Adenuga
- Láti January lọ, gbogbo ẹni tó bá ra ọjà lórí ayélujára yóò máa sanwó orí - FIRS
- Aṣojú Seyí Makinde lásan ní mo jẹ, òṣìṣẹ́ gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún mi - Ọ̀dọ́mọdé Kọmísánà
- Èmi àti Bọla Tinubu fẹ́ lo ‘German Mercenaries’ láti gbé MKO Abiọla kúrò lẹ́wọ̀n - Dele Momodu
- Irọ́ ńlá! Ẹgbẹ́ IPOB ò tako Ààrẹ Buhari ní Japan- Iléeṣẹ́ Ààrẹ
- Òfin nìkan ló lè gbadé lórí àwa Ọba ìlú lbadan- Oba Lekan Balogun
- Irọ́ ló pa, a kò mọ̀ ọ́ rí tàbí fún ọ ní ₦13m - APC tako afurasí ajínigbé
O fí kún pé àwọn atúnṣe kan to yọjú tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ń gbíyànjú láti ṣe àtúnto rẹ, ló fa ìdádúró sísàn owó náà.
Alaga ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tún sàlàyé pé, atunyàn Chris Ngige sípò mínísítà fún ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́, jẹ́ kó mú ọ̀rọ̀ owó òṣìṣẹ́ ni òkúnkúndùn láti rii pe ó di sísàn.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ní ìjọba àti àwọn olórí òṣìsẹ́ ti jà túka lái fẹ́nu ọ̀rọ̀ jọ́nà lórí owó òṣìsẹ́ tó kére jùlọ.








