Ibadan Obaship Tussle: Mọ́gàjí Ibadan ní ìjoba ló da ọ̀rọ̀ lọ́balọ́ba rú

Oríṣun àwòrán, Facebook/Olubadan of Ibadan
O da bi ẹni pe awuyewuye lori awọn Ọba ilu ibadan ko tii loju tu, lẹyin ti ọkan lara wọn, Ọba Lekan Balogun ṣalaye fun BBC Yoruba wi pe ofin nikan lo le yọ awọn nipo gẹgẹ bi ọba ni ilu lbadan.
O ṣalaye pe ofin lo gbe awọn de ori oye fun iparapọ ati ilọsiwaju llu lbadan.
Ọba Lekan Balogun sọ pe ko si aawọ kankan laarin Olubadan ati awọn ọba yoku nitori idagbasoke ilẹ lbadan lo jẹ onikaluku logun.
- Èdè Akurẹ àti Ibadan ni wọ́n fi fà mí léti pé ẹni re kìí 'se òṣèlú - Seyi Makinde
- Ìkúnlẹ̀ àbiyamọ o! Saudi fẹ́ gbẹ̀mí 23 ọmọ Nàìjíríà tó gbé òògùn olóró
- Makinde, jọ̀ọ́ kéde Aug 20 ọdọọdún bíi ọjọ́ ìsinmi fún ìṣẹ̀ṣe - Àwọn oníṣẹ̀ṣe Ọyọ
- Àwọn alálẹ̀ kò ní forí jìn mí tí ń kò bá ṣe ọdún Ṣàngó - Alaafin
- Èmi àti Bọla Tinubu fẹ́ lo ‘German Mercenaries’ láti gbé MKO Abiọla kúrò lẹ́wọ̀n - Dele Momodu
- Ìdẹ̀ra dé, Gẹnẹrátọ̀ tó ń lo omi dé Èdè Akurẹ àti Ibadan ni wọ́n fi fà mí léti pé ẹni re kìí 'se òṣèlú - Seyi Makinde , a bọ́ lọ́wọ́ òkùnkùn
O fikun ọrọ re wi pe ''ọjọ mẹẹdogun-mẹẹdogun ni a maa n ṣe ipade pelu Olubadan.
Ninu alaye rẹ, o sọ siwaju sii pe ''ori ni Olubadan jẹ fun awọn ọba, bẹẹ ni wọn ko si le di iru laelae.''
Ninu ọrọ tiẹ, Mogaji ilu Ibadan, Alhaji Moshood Atẹrẹ sọ wi pe, enikeni ko ti i le sọ pato ibi ti ọrọ naa nlọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Olubadan of Ibadan
Mogaji ilu Ibadan ṣalaye pe lati ọjọ ti ijoba ti tọwọ bọ ọrọ awọn lọbalọba niluu lbadan lọrọ naa ko ti lojutu mọ.
O fi kun ọrọ rẹ pe ijọba kan ti ọwọ bọ ọrọ naa ni, awọn ọba llu lbadan ko ṣetan lati gbe ade wọn silẹ.
Mọgaji llu lbadan sọ pe oye ''His Imperial Majesty'' ti wọn fi n pe Oluban ko ni ohun kan ṣe pẹlu ọrọ to wa nilẹ yii.












