Seyi Makinde: Ìyá Akurẹ àti Iya Ibadan kìlọ̀ fún mi lóru ọ̀gànjọ́ làti sọ́ra fún olóṣèlú

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
Ogbẹni Seyi Makinde, gomina ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe, bi oun ṣe jawe olubori ninu idibo to kọja jẹ ore-ọfẹ Ọlọrun.
Makinde salaye pe iya oun ko fẹ ki oun lọwọ ninu eto oṣelu orilẹ-ede Naijiria rara, nitori igbagbọ awọn eniyan pe awọn oloṣelu kii ṣẹni ire.
Gomina Makinde sọrọ yii nigba to n ṣe idupẹ agbole ni ijọ Aguda Dafidi Mimọ, ti o wa ni Ijọmu, ni ilu Akurẹ, ni ipinlẹ Ondo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àlàyé rèé lórí bí wọ́n ṣe mú mi lẹ́rú ní 1837 - Ajayi Crowther
- Mo nífẹ̀ẹ́ Khafi torí kìí díbọ́n tàbí hùwà oníwà - Gedoni sọ̀rọ̀ ìdágbére
- Wo iléeṣẹ́ ìjọba tí Kọmísánà tuntun kọ̀ọ̀kan ní Ọyọ yóò dìmú
- Àwọn alálẹ̀ kò ní forí jìn mí tí ń kò bá ṣe ọdún Ṣàngó - Alaafin
- Kíni ẹ mọ̀ nípa Tolani Alli, ayàwòrán tí igbákejì ààre Osinbajọ ṣẹ́ṣẹ́ yàn?
O ni oun ko ni baba isalẹ ninu ẹgbe PDP ayafi Ọlọrun ọba. O sọ siwaju pe " Bi mo ṣe duro niwaju yin yii, mo jẹ ẹni ti o de ipo gomina lai ni baba isalẹ, afi Ọlọrun nikan ṣoṣo."
Nigbati mo fẹ bẹrẹ sii kopa ninu eto oṣelu, awọn iya mi mejeji, iya Akurẹ ati iya Ibadan pe mi loru ọganjọ, wọn si kilọ fun mi lede Akure ati ni ede Ibadan pe, ti awọn oloṣelu ba fun mi ni ohun kohun, mi o gbọdọ gbaa."
Wọn sọ eyi nitori igbagbọ wọn pe ẹni ire kan kii sẹgbẹ oṣelu.

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
- O dùn mí pé Buhari kò yàn mí sípò Mínísítà lẹ́ẹ̀kejì àmọ́ mò gbà kádàrá - Adebayo Shittu
- Makinde, jọ̀ọ́ kéde Aug 20 ọdọọdún bíi ọjọ́ ìsinmi fún ìṣẹ̀ṣe - Àwọn oníṣẹ̀ṣe Ọyọ
- Wo ipò tí Buhari fún Faṣọla, Lai Mohammed, Saraki àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
- Ta ni Seun Fakorede, ọmọ ọdún 27 tó fẹ́ di kọmiṣọna?
- Leon van Biljon dí èrò ọrun nípasẹ̀ Kìnìún rẹ̀
Sugbọn bi mo ṣe wa niwaju yin bayi, mo lee sọ kedere pe, ẹni ire lee darapọ mọ eto oṣelu.
Oluṣọ agutan ati oniwaasu nibi idupẹ naa, Simeon Borokini, wa rọ gomina Makinde lati mojuto ọrọ ọgbin, lọna lati gbogun airiṣẹ awọn ọdọ.












