Tongeji Island: Mọ̀ síi nípa ìlú tí omi Ọ̀sà àti omi Yewa yí kà tó wa ní ẹnu bodè Naijiria

Tongeji

Oríṣun àwòrán, bbc

Àkọlé fídíò, Tongeji Island: Mọ̀ síi nípa ìlú tí omi Ọ̀sà àti omi Yewa yí kà tó wa ní ẹnu bodè Naijiria

Tongeji Island ni erekusu ti omi yi ka to wa ni ijoba ibile Ipokia ni ipinle Ogun ni Naijiria.

Ibudo yii lo ti fẹ da ija silẹ laarin Naijira ati orilẹ-ede Benin Republic nitori pe o ba wọn pa aala.

Wọn sọ pe wọn ti ri epo rọbi ninu ilu yii bayii eyi to n ṣi oju awọn eeyan kan sibẹ.

Oba Kabiesi Obabiolorunkosi ṣalaye fun BBC pe oun ti kọwa si ijọba Naijiria lati aye Oloye Obasanjọ gẹgẹ bii aarẹ Naijiria.

Ati pe titi di isinyi ijọba ipinlẹ Ogun ati Naijiria koi ti ṣe nkankan nipe rẹ ṣugbọn awọn ko fẹ ki ọrọ ilu yii di bii ti Cameroon lọjọ ọla.