'Mo ti pé ọgọ́rùn-ún ọdún láyé, àmọ́ ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí mò n lo omi tó mọ́'
Fun awọn olugbe ilu Opi, nipinlẹ Enugu, omi odo to pọn rakọ-rakọ yii ni wọn n pọn lati lo ninu ile wọn.
Lati ọpọlọpọ ọdun si ni wọn ti n lo omi naa, nitori pe ko si ibomiran ti wọn ti le ri omi to mọ daada fun lilo wọn.
Ẹnikan lara awọn araalu naa, Ọgbẹni Michael Okoro,to jẹ ẹni ọgọrun ọdun sọ fun BBC pe lati kekere ni oun ti mọ odo naa, nitori pe awọn obi rẹ ma n gbe e lọ sibẹ lati pọn omi.
Eyi to tumọ si pe gbogbo awọn ọmọ ti wọn n bi sinu ilu naa ko ni anfaani si omi to mọ lati igba kekere ti wọn fi dagba bayii.
Ṣugbọn itan yipada fun awọn araalu Opi, lẹyin ti arakunrin kan, Onyedikachi Erete, gbẹ kangadẹrọ ‘borehole’ fun wọn ninu ilu naa.
Ohun ara to tun wa nipa kangadẹrọ naa ni pe itansan oorun, solar, lo fi n ṣiṣẹ.
Nipa sẹ rẹ si ni awọn araalu naa fi ri omi to mọ fun igba akọkọ.
Ọgbẹni Erete sọ pe lati kekere ni oun ti pinnu lati ma a pese omi fun awọn ilu ati abule ti ko ri omi to dara lo.
“Nigba ti mo kere, a ko ni anfaani si omi to mọ daadaa nile wa. Eyi lo mu ki n pinnu lati da ajọ alaanu silẹ, ti yoo ma a pese omi fun awọn eeyan.”
Tilu-tifọn si ni awọn araalu Opi fi tẹwọ gba kangadẹrọ naa.





