Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fèsì lórí ọ̀rọ̀ táwọn òbí sọ pé òunjẹ táwọn ọmọ àwọn jẹ nilé ẹ̀kọ́ ti bàjẹ́

Aworan ile ẹkọ St. James ati gomina Ademola Adeleke

Ijọba ipinlẹ Osun ti sọ pe kii ṣe ounjẹ tawọn akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ St. James Primary school, l’Osogbo jẹ lo mu wọn dero ile iwosan.

Kọmiṣọnna eto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Osun, Kolapo Alimi, sọ fun BBC Yoruba pe Gomina Ademola Adeleke paṣẹ lẹsẹkẹsẹ pe ki wọn lọ ṣe ayẹwo fawọn ọmọ to jẹ ounjẹ nile iwosan.

''Wọn ṣe bẹẹ, wọn dẹ ri daju pe ko si nkan kan to ṣe awọn ọmọ naa.

Lẹyin naa ni gomina tun paṣẹ pe ki wọn tun lọ ṣe ayẹwo lẹẹkeji nile iwosan ijọba ni Asubiaro lati mọ boya nkan kan ṣe awọn ọmọ yii yala lori ounjẹ ti wọn jẹ nio abi nkan mii.

Awọn yẹn naa yẹ wọn wo, wọn tun ni kosi nkan kan to ṣe wọn.

Gomina tun paṣẹ pe ki wọn tun kawọn ọmọ naa lọ si ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun fasiti ipinlẹ Osun, UNIOSUN lati tun lọ ṣe ayẹwo fun wọn, bakan naa ni wọn tun sọ pe ko si nkan kan to ṣe wọn,'' kọmiṣọnna ṣalaye.

Họnọrebu Alimi fikun ọrọ rẹ pe ''awọn ọga ile ẹkọ yẹn sọ pe gbogbo ounjẹ ti wọn maa n gbe wa sile ẹkọ naa lawọn maa n yẹwo kawọn ọmọ to bẹrẹ si ni jẹ ẹ,''

Awọn alaṣẹ ile ẹkọ yii tun ṣalaye pe laarin ago mọkanla si mejila lawọn ọmọ ile ẹkọ maa n jẹun, ko si si ọmọ to sọ pe inu n run oun ti wọn fi lọ sile nibi ago meji.''

Kọmiṣọnna ni ''pẹlu gbogbo iwadii ati ayẹwo awọn dokita, kii ṣe ounjẹ tawọn ọmọ yii jẹ lo ṣe okunfa inu to bẹrẹ si ni run lalẹ.

Idi ni pe nkan kan ko ṣe awọn olukọ to jẹ ounjẹ kan naa tawọn ọmọ yii jẹ, inu ko run wọn, ati pe awọn ọmọ to jẹ ounjẹ yii le lọgọrun.

Awọn ọmọ ti wọn dero ile iwosan yii, adugbo kan naa ni gbogbo wọn ti wa.

Bo ya nigba ti wọn n lọ ile ni wọn ra nkan jẹ loju ọna eyi to n mu inu run wọn lalẹ.

Ijọba lo san owo itọju awọn ọmọ naa nibi ti wọn kọkọ gbe wọn lọ.''

Họnọrebu Alimi wa rọ awọn obi pe ki wọn maa mojuto awọn ọmọ wọn ki wọn kan ma maa jẹ oniruuru nkan.

Kọmiṣọnna ni ijọba tun ti kọ ẹkọ sii lori iṣẹlẹ yii, ijọba yoo tubọ maa ṣe ayẹwo awọn to n se ounjẹ lawọn ile ẹkọ yii finifini.

Lori ọrọ ti obi kan sọ pe awọn ọmọ to dero ile iwosan ju mejidinlogun lọ, kọmisọnna ni mejidinlogun ni wọn.

Ọmọ mi mẹ́ta ló wà lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 18 tó dèrò ilé ìwòsàn l’Osun lẹ́yìn tí wọ́n jẹ oúnjẹ ìjọba - Òbí

Irewumi Omolara to jẹ iya ọmọ mẹta lara awọn akẹkọọ mejidinlogun ile ẹkọ St. James Primary school, Osogbo to dero ile iwosan lẹyin ti wọn jẹ irẹsi ati ẹyin nile ẹkọ naa ti sọ pe, bi awọn ọmọ oun ti de lati ile ẹkọ ni ọjọ na ni wọn ti bẹrẹ si ni pariwo inu rirun.

Arabinrin Omolara ti fi idi rẹ mulẹ pe, lowurọ ọjọ Aje ti awọn ọmọ oun ń lọ si ile ẹkọ wọn, oun ko fun wọn ni ounjẹ rara ki wọn to kuro nile lọjọ na.

Omolara ni ''nigba na ni mo beere lọwọ wọn pe kinni wọn fun wọn jẹ ile ẹkọ wọn, ti wọn si sọ pe irẹsi ati ẹyin to ti bajẹ lawọn jẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bí wọn se sọ ọrọ naa tan ni mo kọkọ fun wọn ni agbo tí Ìbílẹ̀ na, eyi si mu wọn ya igbẹ.

Nigba naa ni awọn ijọba de tì wọn si ko wọn lọ sí ile iwosan ti Fáṣítì Ọsun.

Ki se ọmọ mejidinlogun ni iṣẹlẹ na sẹlẹ si rara.

Awa obi ti a pade nile iwosan ju Ọgọrun lọ.

Akọwe iroyin fun gomina ipinlẹ Osun, Olawale Rasheed duro lori ẹsẹ rẹ pe mejidinlogun lawọn ọmọ naa.

Tunrayo Osunniyi ti oun naa jẹ ọkan lara awọn obi ọmọ yii sọ pe ara awọn ọmọ naa ti ya bayii.

O wa rọ ìjọba lati maa se amojuto awọn ti wọn gba lati maa gbe ounjẹ wa fun awọn ọmọ.

Obi miiran, Kudirat Fatai ni ki se agbo ile kan ni awọn ọmọ tí iṣẹlẹ naa sẹlẹ si ti wa.

Kudirat ro ìjọba lati se iwadii lori iṣẹlẹ naa ko maa ba waye mọ.

Ọmọ kan ni ọmọ oun ti iṣẹlẹ naa sẹlẹ si sugbọn o ti gba itoju nile iwosan ti ìjọba ko wọn lo.

Komisọnna fun eto Iroyin ni ipinle Ọsun, Kolapo Alimi to fi idi iṣẹlẹ na mulẹ sọ pe iwadii n lọ lọwọ.

Kolapo Alimi rọ gbogbo awọn obi ti ọmọ wọn fi ara gba ninu iṣẹlẹ naa pa, ki wọn ko ma bẹru rara ati pe ìjọba ti n gbe igbesẹ.

Ile iwosan ti wọn ti tọju awọn ọmọ naa kọ lati ba BBC Yoruba sọrọ.