Ayálégbé jí ọmọ onílé gbé lọ l'Ogun, wo nkàn tí òfin sọ pé kí ònílé máa yẹ̀wò kó tó gba èèyàn silé

Aworan ayalegbe to n ka iwe adehun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹni ti yoo ba parọ ni yoo sọ pe ẹlẹri oun ko si ni tosi.

Apilẹkọ wa yi to da lori nkan ti ofin sọ pe ki onile ṣe gẹgẹ bi iṣọra ki o to gbe ile kalẹ fun ayalegbe ko ṣadede waye.

Bi kii ṣe pe iṣẹlẹ kan to waye nipinlẹ Ogun lo mu wa ni ka ta araalu lolobo oogun iṣọra taa le fi dena iru rẹ lọjọ iwaju.

Iroyin taa n sọ yi waye ni ipinlẹ Ogun laipẹ yi ti ileeṣẹ ọlọpaa si fidi rẹ mulẹ pe lootọ lo waye.

Arabinrin kan lo ṣadede gbe ọmọ ọkunrin onile ati ti alabagbe rẹ gbe salọ lẹyin ọjọ kẹtaa ti wọn gba a sile.

Titi di akoko taa n ṣe akojọpọ iroyin yi, wọn ko le sọ pato ibi ti obinrin naa poora si.

Adugbo Sango Ota lo ti ji awọn ọmọ gbe salọ.

Ohun ti ọlọpaa sọ ni pe lanrilọọdu to nile, Johnson Oshinowo, lo mu ẹjọ wa sọdọ awọn pe arabinrin kan ti oun gbe ile fun lọjọ Keje oṣu Kejila ọdun taa wa ninu rẹ yi ti gbe ọmọ rẹ ati ti ayalegbe mii ti wọn jẹ ọmọ ọdun mẹrin salọ.

O ni awọn ko ni idanimọ kankan to le tọka si obinrin yi tori pe ẹni to ṣe atọna bi wọn ṣe gbe ile fun iyẹn ''agent'' ko ṣe ayẹwo finfini ko to mu wa lati gba ile lọdọ rẹ.

Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii bonkẹlẹ lati mọ ibi ti obinrin yi sa pamọ tabi poora si.

Amọ ṣa baba ọlọmọ ati ayalegbe keji ti wọn gbe ọmọ wọn salọ wa ninu ibanujẹ ohun ifoya lori ohun to ti ṣẹlẹ yi.

O sunmọ ki ọkan yin ti maa tọka si idi taa fi fẹ ṣe agbekalẹ apilẹkọ yi bayii abi?

Ẹ jẹ ka jọ gbọ lẹnu awọn onimọ nipa ofin to rọ mọ ile gbigba ohun to yẹ ki onile ṣe gẹgẹ bi igbesẹ ṣaaju ko to gba eeyan sile gẹgẹ bi ayalegbe ni Naijiria.

Ibeere ṣe pataki, ko si si ibeere kankan to ṣe foju di

Aworan afihan ile ti wọn fẹ gbe kalẹ

Oríṣun àwòrán, Getty

Onimọ nipa ofin taa kan si lori ọrọ yi, Agbẹjọro Adebisi Iyaniwura sọ pe akọkọ nkan to yẹ ni ki onile mu kan pe oun yoo beere ọrọ debi to mu itẹlọrun wa ki o to le gba eeyan sile gẹgẹ bi ayalegbe.

O sọ pe awọn ibeere, kilorukọ rẹ, nibo lo ti wa, iṣẹ wo lo n ṣe, Njẹ o ni iyawo ati ọmọ, ọkọ nkọ ati bẹẹ bẹẹ lọ lawọn eeyan a maa foju di lae mọ pe awọn wọnyi ṣe pataki lati le mọ nipa ayalegbe.

''Bi awọn to ba mu ayalegbe wa si ọdọ yin ba sọ pe awọn mọ ẹni naa. Ẹ sọ pe ẹ ti gbọ ṣugbọn ẹyin naa fẹ mọ nipa rẹ si.Bi eeyan ko ba ti kọkọ tiju lati beere ọrọ lọwọ ẹni to fẹ gba ile, abuṣe ti buṣe.''

Lọpọ igba awọn onile a maa gbe fọọmu le ayalegbe lọwọ pe ko dahun awọn ibeere taa ka siwaju yi sinu rẹ.

Iyaniwura sọ pe ti wọn ko ba le dahun awọn ibeere yi ko mu itẹlọrun wa, atọka ree wi pe ki eeyan sọra ko tole gbe ile fun iru ẹni bẹẹ.

Ma fi ti esi ti wọn kọ silẹ nikan ṣe, tẹsiwaju lati ṣe iwadii tiẹ naa

Agbẹjọro yi to fi ilu Eko ṣe ibujoko sọ pe ti ẹni to n wa ile ba kọawọn esi yi tan, ojuṣe onile ni lati ṣe iwadii lati mọ boya ohun to kọ silẹ jẹ otito.

O ṣalaye pe eyi ṣe dandan nitori bi ọrọ aburu kankan ba ṣẹlẹ, ẹni to gba eeyan sile naa ko le moribọ nibẹ.

''Labẹ eleyi, o ṣe pataki lati ṣe iwadii ki ẹ si jẹri awọn esi to jọ mọ ibi ti ẹni yi sọ pe ohun ti n ṣiṣẹ, awọn to pe ni mọlẹbi rẹ ati an nkan mii.Bi ẹ ba de sọọbu to loun tio n taja, ẹ fọgbọn beere boya oun lo ni ṣọọbu naa tabi o si n ba eeyan mojuto ni.Gbogbo awọn nkan wọnyi yo le yọ okun wahala kuro lọrun yi lọjọ iwaju ti ọrọ ba gbọna mii yọ''

Ni pataki, Iyaniwura sọ pe ki onile gba aworan pelebe ẹni to fẹ gba ile ko si ri wi pe awọn eeyan jẹri si wi pe awọn mọ ẹni to wa ninu aworan naa.

O ni aworan yi lo le jẹ ki wọn wa ẹni naa bi iru arabinrin to ji ọmọ gbe yi ti awọn onile sọ pe awọn ko ni iroyin kankan nipa rẹ.

Awọn oniduro naa ṣe pataki

Yoruba bọ wọn ni abẹrẹ ti ko lokun nidi lo maa n sọnu.

Amofin to ba wa sọrọ ṣalaye pe onile gbọdọ mọ awọn to ṣe oniduro fun eyikeyi ayalegbe to fẹ gbe inu ile rẹ.

O ni fifi oju awarawa wo ọrọ ile gbigba kii lẹhin ati pe eleyi lomaa n koba ọpọ eeyan ti ọrọ ba yiwọ tan.

''Ẹgbọn mi lo mu wa. Aburu mi ni ẹ ba mi gba sile. Gbogbo awọn ọr bayii lo maa n mu ki awọn onile ma le tọ ayalegbe to ba na papa bora.''

Lọpọ igba bo ṣe ṣalaye, awọn oniduro a maa sọ pe aburo adugbo ni ẹni tawọn duro fun, ti eleyi ko si bofin mu.

O fikun pe bi wọn ṣe n se iwadii lori ẹni to fẹ gba ile naa lo ṣe ṣe pataki lati m ile ati ọna awọn to ṣe oniduro fun wọn.

Iyaniwura sọ pe bi wọn ba ṣe gbogbo igbesẹ yi tan ki wọn tun fi adura si ki wọn ma ba dowopọ pẹlu alakoba alaburu ẹda.