Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ ọkọ̀ àti ọ̀kadà tí àwọn adigunjalè fi fọ́ báńkì l’Ekiti

Oríṣun àwòrán, screenshot
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti ni awọn ti ri ọkọ mẹta ati ọkada meji ti awọn igara ọlọṣa to sọṣẹ ni awọn banki kan ni ipinlẹ naa lọjọru.
Eeyan mẹta ni awọn adigunle naa yinbọn pa lasiko ti wọn digun ja awọn banki lole nilu Ikẹrẹ Ekiti.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti fi sita loju opo X rẹ ṣalaye pe awọn ọlọpaa ti n wa awọn ọdaran naa lẹyin ti wọn sa fi ọkọ ati ọkada ti wọn fi jale naa silẹ.
Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti, Ogundare Dare ti rọ awọn eeyan to ba ni iroyin to le ran ọlọpaa lọwọ lati mu awọn adigunjale naa lati tete fi to ọlọpaa leti.
O ni awọn ọlọpaa at'awọn ologun ti tẹsẹ bọ wiwa awọn ọdaran naa.
Àlàyé rèé lórí bí àwọn adigunjalè ṣe fọ́ báńkì lọ́sàn án Ọjọ́rú ní Ikere Ekiti níbi tí ẹ̀mí ti sùn

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Ọsan gangan ni awọn igara ọlọṣa naa ṣe ikọlu sile ifowopamọ meji nipinlẹ Ekiti l’Ọjọru ọsẹ yii nibi tawọn eeyan kan ti padanu ẹmi wọn, ti ọpọlọpọ si farapa.
Iṣẹlẹ laabi ọhun tawọn eeyan juwe bii ohun to buru jai, lo waye nilu Ikere-Ekiti to jẹ ọkan lara awọn ilu to gbajumọ julọ nipinlẹ naa.
Oṣojumikoro kan to fẹẹ wọ ọkan lara awọn banki naa nigba ti iṣẹlẹ naa sọ wi pe ko din ninu eeyan mẹta to padanu ẹmi wọn sinu akọlu naa tawọn kan si farapa.
Ileefowopamọ meji to gbajumọ ni awọn ọlọṣa naa wọ lọwọ irọlẹ ti wọn de si agbegbe naa ti wọn si n fi ado ibugbamu fọ ilẹkun awọn banki naa.
Ado oloro lawọn adigunjale naa lo
Ado ibugbamu yii lo fun wọn laaye lati lee wọle sinu awọn banki naa nibi ti onibara ati oṣiṣẹ banki wa.
Bi awọn eyan ṣe n gbiyanju lati sa asala fun ẹmi wọn nitori ibẹrubojo to ba wọn latari ariwo ibugbamu naa ni awọn alọkolohunkigbe ọun ṣina ibọn bolẹ, ti wọn si bẹrẹ iṣẹ wọn.
BBC gbọ pe awọn adigunjale naa kọkọ bẹrẹ si nii yinbọn nita banki ọhun lati fi le awọn eeyan sẹyin.
Alupupu ni awọn adigunjale naa gbe waa ki wọn too fibọn le awọn eniyan sẹyin ti wọn si ji ọkọ kan ti owo wa ninu rẹ lọ.
Oṣojumikoro kan naa wi pe awọn adigunjale naa pin awọn ọmọ ẹgbẹ wọn si oju popo ki wọn maa ṣọ awọn to ba n bọ nigba ti awọn to ku n pa itu meje ninu ile.
“Wọn ko yinbọ si ẹnikẹni ninu banki. Wọn kan n yinbọn soke ni titi ti wọn fi lọ.”


“Inu igbo ni wọn gba sa lọ”
Gẹgẹ bi ajọ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ṣe wi, wọn ti bẹrẹ si nii wa awọn adigunjale naa.
Kọmiṣọna ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Dare Ogundare, awọn ko nii sinmi ti awọn ọdaran naa ko ba wọ ẹwọn.
Ogundare wi pe “nigba ti awọn ọlọpaa atawọ ologun de banki naa, awọn adigunjale naa kọju ibọn si wọn.
“Nigba to ya, awọn ọlọṣa naa fi awọn ọkọ mẹta ati alupupu meji ti wọn gbe lọ silẹ, wan si bẹ wọ’gbo. A si ti ko awọn ọkọ ati alupupu naa lọ agọ wa.”
Bi wọn ṣe tẹsiwaju lati maa wa awọn adigunjale naa, awọn ọlọpaa ti rọ awọn araalu lati fi ọkan bale, ki wọn si fi ohunkohun ti wọn ba mọ nipa awọn to ṣiṣẹ laabi naa to awọn alaṣẹ leti.
Ikere Ekiti Robbery: Ìgárá ọlọ́sà fọ́ báńkì, ẹ̀mí bọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn farapa
Ọpọlọpọ eniyan ni wọn fi ara pa ti oku si sun ninu ikọlu adigunjale ile ifowopamo meji to waye ni ọjọ kẹtala oṣu kejila, odun 2023 ni Ikere Ekiti, ipinle Ekiti.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti fidi iṣẹlẹ yi mulẹ ti wọn si ni kawọn araalu ma foya wi pe awọn yoo tọ pinpin awọn to wa nidi iṣẹlẹ aburu yi.
Kọmiṣana ọlọpaa nipinlẹ Ekiti ṣabẹwo si awọn banki ti awọn adigunjale yi ṣe ikọlu si lẹyin iṣẹlẹ naa.
Ninu atẹjade ti alukoro ọlọpaa Ekiti Abutu Sunday fi sita,o ni awọn ikọ ọlọpaa ati awọn ọmọ ogun to tara lọ koju awọn adigunjale yi lo mu ki wọn fi ọkọ wọn mẹta ati alupupu meji silẹ ti wọn si na papa bora.
Atẹjade naa ko sọ iye ọlọpaa ati araalu to ku ninu iṣẹlẹ naa amọ o sọ pe Kọmiṣana n kẹdun pẹlu mọlẹbi awọn to padanu ẹmi ati awọn to farapa.
Ohun tawọn oṣoju mi koro ṣọ fun akoroyin wa
Gege bi awọn ti isele naa se oju wọn lagbegbe naa ṣe sọ fun akọroyin wa,nkan bi ago mẹrin irọlẹ ni awọn adigunjale naa de banki Wema to wa ni Oke-kere Ikere Ekiti.
Wọn ni bẹẹ naa ni wọn bẹrẹ si ni yinbọn soke ti wọn si tun yin afẹfẹ taju-taju lati fi dẹru ba awọn eeyan.
Pabo ni gbogbo igbiyanju awọn adigunjale naa ja si pẹlu bi wọn ko ṣe ribi wọle si banki naa amọ wọn pa awọn eniyan kan ninu rogbodiyan naa.
Leyin naa ni awon adigunjale na kuro ni ile ifowopamo Wema banki Oke-kere lo si Oke-Osun nibi ti won ti kolu eka banki Access to wa nibe, ti won si pa awon agbofinro ti won si ko ọpọlọpọ owo lọ.
Bakan naa ni wọn sọ wi pe awọn adigunjale naa ju awọn ohun ija oloro silẹ kakiri ni ilu Ikere ni asiko ikọlu naa ti o si ba ọpọ dukia jẹ.
Banki fifọ kii ṣe nkan ajoji l'Ekiti
Kaakiri oju opo ayelujara lawọn eeyan n ṣalabapin fọnran fidio to ṣafihan awọn adihunjale naa nigba ti wọn n ṣọṣẹ ati lẹyin ti wọn kuro lawọn ile ifowopamọ ti wọn kọlu.
A ko le fidi rẹ mulẹ wi pe awọn fọnran yi jẹ ti ikọlu si banki to waye amọ ṣaaju asiko yi, akọsilẹ wa to tọka si pe awọn adigunjale ko ṣẹ́ṣẹ maa kọlu awọn ile ifowopamọ nipinlẹ Ekiti.
Bi awọn araalu Oye Ekiti, Aramoko ati Iyin Ekiti ṣe n ṣalabapade awọn igara ọlọsa yi naa ni ẹmi araalu ati ọlọpaa ṣe n ba ikọlu wọn lọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ko ti sọ pato iye awọn to ba iṣẹlẹ to waye yi lọ bẹẹ si ni wọn ko sọ iye owo tawọn ole naa gbe salọ.
Ọrọ aabo jẹ nkan to n kan ọpọ lominu ni Naijiria ni paapa awọn ipinlẹ iw oorun Guusu Naijiria.
Bi wọn ko ba maa ke irora ajinigbe wọn a tun maa foya lori ọrọ awọn adigunjale.
O buru debi pe awọn Gomina ipinlẹ ilẹ kaarọ o jiire yatọ si Eko ṣe idasilẹ ikọ alaabo abẹle ti wọn n pe ni Amọtekun.
Igbiyanju awn ikọ yi ati agbofinro n ṣe diẹ ṣugbọn ko dabi ẹni pe o ribi dẹkun patapata awn alaburu to n da omi alaafia ilu ru.















