Gbogbo ìgbà làwọn ọmọ mi máa ń bèrè ìdí tí mi ò fi lè rìn – Yinka Ayefele

Yinka Ayefele

Oríṣun àwòrán, Yinka Ayefele

Gbajugbaja olorin tungba, Yinka Ayefele ti ni diẹ lo ku ki omijẹ bọ loju oun lẹyin ti awọn ọmọ rẹ bere lọwọ rẹ, eredi ti ko fi le dide.

Ninu fidio kan ti olorin ọhun fi lede loju Instagram rẹ ni awọn ọmọ naa ti n bere bẹẹ lọwọ rẹ.

Fidio ọhun ṣafihan olorin naa, pẹlu awọn ọmọ rẹ ninu yara ti wọn si n ni ifọrọjomitoro ọrọ.

Ọkan lara awọn ọmọ rẹ naa, Richard ni “Baba mi, ki lo de ti ẹ ko le dide?”

Ti Ayefele si da lohun pe ijanba ọkọ kan ti oun ni lọpọ ọdun sẹyin ni ko jẹ ki oun le dide bi awọn ẹlọmiran mọ.

Ayefele ni “Mi o le rin nitori ijanba ọkọ ti mo ni lọpọ ọdun sẹyin.

“Ọjọ kejila, oṣu Kejila, ọdun 1997 lasiko ọdun Keresimesi ni ijanba naa waye.

“Emi ni mo n wa ọkọ ṣugbọn ọna naa n yọ.

“Eredi ree ti ọkọ mi fi takiti nigba mẹfa ọtọtọ ko to lọ fori sọ koto ninu igbo.

“Awọn eeyan to wa layika lo gbe mi digbdigba lọ sile iwosan, ki n to lọ gba itọju nile iwosan Royal National Orthopaedic Hospital, to wa niluu London.”

Mo gbagbọ pe mo ṣi maa rin

Bo tilẹ jẹ pe Ayefele gbiyanju lati ṣalaye idi ti ko fi le dide tabi rin fun awọn ọmọ rẹ, ọrọ ọhun ko fi bẹẹ ye wọn taara nitori ọjọ ori wọn.

Amọ ṣa, o jẹ ko ye wọn pe oun gbagbọ pe oun ṣi maa rin lọjọ kan.

O ni “Inu rẹ ko dun nitori mo ni ijanba ọkọ abi?

“Ṣugbọn mo gbagbọ pe mo ṣi maa rin.”