"Ọ̀wọ́ngógó òògùn òyìnbó lásìkò yìí ti mú kí ayédèrú òògùn pọ̀ ní ìgboro"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pẹlu bi awọn oogun oyinbo ṣe gbowo lori ju ti tẹlẹ lọ jakejado Naijiria, awọn ayederu oogun lo ti waa pọ nigboro ju ti atẹyinwa lọ, leyi to mu ki ajọ to n moju to ounjẹ ati oogun (NAFDAC) o maa kọminu.
Iwoye awọn agba ọjẹ nidi eto ilera ni pe awọn aisan, ipalara ati iku to wọpọ lẹnu ọjọ mẹta yii le ma ṣẹyin bi awọn kan ṣe n ta ayederu oogun bii ojulowo fun lilo awọn araalu.
Iwadii fihan pe ajọ NAFDAC ni ko ni agbara to lati kapa tita ayederu oogun lori igba pẹlu bi wọn ko ṣe ni oṣiṣẹ to, gbigabowo ti ko to latọdọ ijọba ati aile bojuto ọja to lori igba jakejado Naijiria.
Yatọ si sisan owo oṣu, ajọ naa ni ko ni ajẹṣẹku to lati fi mojuto oogun to le ni ẹgbẹrun mejindinlọgọta kaakiri origun mẹrẹrin Naijiria.
Ninu atẹjade kan ti ajọ iṣọkan agbaye to n moju to oogun ati iwa ọdaran (UNODC) gbe jade laipẹ, wọn wi pe ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta lawọ eeyan ti ayederu oogun n ṣekupa laarin ọdun kan ni Naijiria atawọn orilẹede kan ni Afirika.
Awọn bii ẹgbẹrun mẹtadinlaadọrinlenigba ni ayederu oogun iba n ran lọrun aremabọ, ti awọn to le ni ẹgbẹrun mọkandinlaadọsan si b padanu ẹmi wọn nitori ayederu oogun ti wọn fi n tọju otutu aya awọn ọmọde.
Bakan naa ni NAFDAC ti ke gbajare nipa ayederu oogun ikọ, oogun agbogun ti kokoro, atawọn oogun ọmọde miran to gba igboro kan.
Ẹwẹ, ọja oogun lo ti di oogun owo fun awọn alayaderu oogun ni bi gbogbo nkan ṣe gbowolori, paapaa julọ awọn oogun oyinbo ti oye owo wọn ti le ni ida ọọdunrun ju ti oṣu mẹfa sẹyin lọ, leyi to fun wọn laaye lati maa ko ayederu wọle lati oke okun.
'A nilo awọn oṣiṣẹ sii'

Oríṣun àwòrán, X@NafdacAgency
Ọga agba ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye, wi pe gbogbo ipenija ti ajọ naa n doju kọ ni yoo dopin laipẹ ti ijọ ba ṣe atilẹyin to yẹ fun wọn.
Adeyeye wi pe lati lee moju to awọn oogun nigboro bo ṣe yẹ, ajọ naa yoo gba oṣiṣẹ sii, ti wọn yoo si ṣe gbogbo ironilagbara to yẹ fun wọn.
O wi pe “A nilo oṣiṣẹ sii. Ni ileeṣẹ wa nipinlẹ kan, oṣiṣẹ mejila pere lo wa nibẹ, taa si n reti pe ki wọn ṣe ọpọlọpọ iṣẹ bii iforukọsilẹ, amojuto ati bẹẹ bẹẹ lọ.
“Bii ẹgbẹwa ni gbogbo oṣiṣẹ taa ni bayi, amọ ko too di ipari ọdun 2024 abi 2025, o maa to bii ẹgbàajì.
“A maa ṣe afikun si ohun to wa nilẹ bayii amọ a n gbaa ladura pe ki ijọba o fi owo to jọju ṣe iranwọ fun wa.”
'NAFDAC ni lati fi kun ipa wọn'
Aarẹ ẹgbẹ awọn akọṣẹmọṣẹ apoogun nilẹ yii nigba kan ri, Olumide Akintayo, wi pe bi amojuto oogun ko ṣe fẹsẹ rinlẹ daadaa ni Naijiria lo n fa awọn ipenija bii ayederu oogun ati aṣilo oogun, leyi toti di eegun nla to ha eto ilera lọfun.
Apoogun naa wi pe “Lori iwe, ẹ o ro pe owo to jọju wa fun NAFDAC, amọ wọn lee ṣe ju bẹẹ lọ. Ijọba ni lati lo awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ lati ṣe atilẹyin fun NAFDAC ki wọn lee ba awọn aaye ti wọn ti n ṣe ayederu oogun jẹ nilẹ yii ati loke okun”.
Ọga agba ileeṣẹ apoogun Emzor, Dokita Stella Okoli, sọ fun awọn akọroyin pe “NAFDAC n gbiyanju amọ wọn ni lati fi kun ipa wọn.
“Wọn ni lati moju to awọn oogun lori igba ju ju ti tẹlẹ lọ ki Naijiria ati iwọ-oorun Afirika o ma di aatan ti wọn da ayederu oogun si.”













