Tó bá jẹ́ pé mo ríran ni, iṣẹ́ bọ́ọ̀lù gbígbá ni mi ò bá yàn láàyò - ọ̀dọ́mọdé akàròyìn eré ìdárayá

Àkọlé fídíò, ''Tó bá jẹ́ pé mo ríran ni, iṣẹ́ bọ́ọ̀lù gbígbá ni mi ò bá yàn láàyò''
Tó bá jẹ́ pé mo ríran ni, iṣẹ́ bọ́ọ̀lù gbígbá ni mi ò bá yàn láàyò - ọ̀dọ́mọdé akàròyìn eré ìdárayá
Aworan Abdulfatai Rofiq

Njẹ ẹyin ti gbọ nipa akaroyin ere idaraya to ni ipenija oju ri?

Abdulfatai Rofiq ree ti awọn eeyan mọ si 'The Sportscaster'.

Ọga ni Rofiq nipa ṣiṣe agbekalẹ gbogbo bi o ṣe n ṣẹlẹ lagbo ere idaraya.

Ọmọ bibi ilu Ilorin ni Rofiq, o sí tun jẹ akẹkọọ ile ẹkọ Mueen College to wa ni Iga Saka lọwọ lọwọ.

Rofiq ni "gẹgẹ bi itan ti wọn ma n sọ fun mi nigba ti mo dagba, wọn jẹ ko ye mi pe wọn o bi mi láì ríran.

Wọn ni igba ti mo pe ọmọ ọdun lo bẹrẹ botilẹ jẹ pe wọn gbiyanju nigba ti oju akọkọ lọ pe ki ikeji má lọ.

Ṣugbọn ko ju ọsẹ kan si igba yẹn ti ẹlẹẹkeji fi lọ.

Awọn obi mi sare lasiko igba yẹn to fi jẹ pe wọn o ri ojutu si mọ.

To ba jẹ pe mo ni a anfani lati riran nii, bọọlu alafẹsẹgba oun ni mo fẹ gba ṣugbọn ko bami ninu jẹ tori mo tun wo pe ona mi wo ni mo tun le fi wulo fun awujọ wa ati gbogbo agbaye ìdí niyi ti mo fi yan lati ma sọ awọn iroyin ere idaraya lati ma sọ lore kore ki awọn eeyan si ma gbọ bi o ṣe n lọ.

Afojusun mi lọjọ iwaju ni lati ka iwe de fasiti lati gba oye ijinlẹ ki n si di ogbontarigi nidi kika iroyin ere idaraya, ati igba ti mo pe ọmọ ọdun mọkandinlogun ni mo ti nifẹ lati maa ṣe iroyin ere idaraya, o wun mi lati di gbajugbaja ti awọn eeyan a mọ bi ẹni to n sọ iroyin ere idaraya nilẹ yii ati loke okun.''