Ìjàmbá ọkọ̀ mú ẹ̀mí èèyàn mọ́kànlá lọ lójú ọ̀nà márosẹ̀ Eko sí Ibadan

Oríṣun àwòrán, FRSC Ogun
O kere tan, eeyan mọkanla ti jade laye latari ijamba ọkọ kan to waye loju ọna marosẹ ilu Eko si Ibadan.
Iroyin ni nnkan bii aago marun un idaji ọjọ Iṣẹgun ni ijamba naa waye, eyii to kan ọkọ akero Toyota Haice to ni nọmba FKY898YF to n bọ lati ilu Kano, ati ọkọ ‘Tipper’ ti wọn fi n ko yanri.
Ninu atẹjade kan ti Florence Okpe, to gbẹnusọ ajọ FRSC ipinlẹ Ogun fi lede, o ni apapọ eeyan mejidinlogun ni ijamba naa kan.
Atẹjade ọhun ni ọkunrin ni gbogbo awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ, nigba ti awọn ọkunrin meje mii farapa yanayana.
Okpe sọ pe ni kete ti iroyin ijamba naa to awọn leti ni wọn sare tete lọ sibẹ lati doola awọn ti ọrọ naa kan, ti wọn si ko awọn to ṣeṣe lo sile iwosan Famobis to wa niluu Ibafo.
Eeyan mẹwaa lo kọkọ jade laye ninu ti ijamba ọhun, ti ajọ FRSC si ko wọn lọ sile igbokupamọsi kan to wa niluu Sagamu.
Amọ oṣeni laanu pe lẹyin ti wọn ko awọn meje to ṣeṣe de ile iwosan tan ni ọkan lara wọn tun jẹ Ọlọrun nipe, eyii to mu ki apapọ iye eeyan to jade laye pe mọkanla.
FRSC ni ijamba naa iba ma ti waye to ba jẹ pe awọn awakọ ti ọrọ kan ṣe awọn nnkan to yẹ ki wọn ṣe.
Ajọ naa wa gba awọn awakọ niyanju ki wọn maa sinmi iṣeju mẹẹdogun o kere tan, lẹyin ti wọn ba ti wa ọkọ fun wakati mẹrin.
Lẹyin naa lo ba mọlẹbi gbogbo awọn to jade laye atawọn to farapa kẹdun.














