Àkọsílẹ̀ wákàtí ìkẹyìn fún Danielle àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ kí Hamas tó ṣekú pa wọ́n

Oríṣun àwòrán, Eyal Waldman
- Author, By Orla Guerin,
- Role, BBC News
- Reporting from, Tel Aviv
Danielle Waldman jo ijo ajokẹyin rẹ nile aye lọjọ keje oṣu kẹwaa.
Ko pẹ diẹ sii ni oun atwọn ọrẹ rẹ bẹrẹ si nii sa asala fun ẹmi wọn amọ wọ ko mori dele.
Akọọlẹ wa fun awọn wakati ikẹyin rẹ - fanaran kekere kan ti wọn fi foonu ya, ti BBC si ti ri. Eleyi lo ṣafihan die lara aburu to n bọ niwaju.
Ọmọ ọdun mẹrinlelogun naa lo joko sẹyin ọkọ pẹlu awọn ọrẹ rẹ meji – ti irun rẹ gigun si n yọ labẹ aṣọ otutu to wọ. Awọn mẹtẹẹta o fi bẹẹ mura ju. Wọn n gbiyanju lati rẹrin pẹlu agidi, wọn si n paruwo. Wọn wọ ẹgbawọ buluu lati ibi ajọdun orin ‘Supernova’ ti wọn ṣẹṣẹ lọ.
Wọn gbiyanju lati farabalẹ amọ o ni nkan to n le wọn.
Noam Shai, to jẹ ọrẹkunrin Danielle, lo n wakọ naa.
“Ṣe ẹ fẹẹ ki n sare, ere gidi?” lo beere. “Mo mọọ ṣe o.”
“O daa bẹẹ,” ni ọkan lara awọn obinrin naa fi fun un lesi. Ọdọmọkunrin kan to joko lẹgbẹ Danielle gbiyanju lati fi wọn lọkan balẹ. O wi pe “gbogbo rẹ yoo dara. Ko si wahala, abi?”
Lojiji, ibeere wa lati tiwaju – “soi abi ọtun?”
Bẹẹ ni fanran naa pari.

Oríṣun àwòrán, Family handout
Lẹyin iṣẹju diẹ, awọn agbebọn Hamas fi ọta ibon dabira si ọkọ naa lara. Noam, Danielle, atawọn ọrẹ wọn to wa lẹyin ọkọ ni wọn pa. – bẹẹ naa bi wọn pa awọn bii ọtalelọọdunrun awọn ọmọ Israel ti wọn lọọ jo nibi ajọdun to waye ni aṣalẹ Negev nitosi Gaza.
Wọn si mu ẹni to joko lọwọ iwaju si igbekun.
Nigba ti oorun yoo fi wọ lọjọ taa wi yii, ẹgbẹfa ọmọ Israel ni wọn ti pa – yala nibi ajọdun ọhun abi ninu ile wọn ni Kibbutzim nitosi ibode. Eyii ni adanu ẹmi to pọ julọ fun awọn Juu lati igba ti wọn ti pa ogunlọgọ wọn nigba ogun agbaye keki laarin ọdun 1941 sui 1945.
Lati igba naa wa, Israel lo bẹẹrẹ ogun ni Gaza lati fopin si Hamas, to si mu ki ọgọọrọ ọmọ Palestine o maa padanu ẹmi wọn.
O to ẹgbẹrun mejidinlogun eeyan ti wọn ti pa – gẹgẹ bi ileeṣẹ feto ilera ni Gaza ṣe wi – ti ẹgbẹrun meje ninu wọn si jẹ ọmọde.
Ni Gaza bayii, bo ṣe wa ni Israel lati ọjọ keje oṣu kẹwaa, awọn obi lo n sinku awọn ọmọ wọn. Fun awọn abi yii, yala wọn jẹ ọmọ Palesstine ni abi Israel, adanu yii n ni koṣee ko.
A ba Eyal, to jẹ baba Danielle, ninu ọfiisi rẹ ni Tel Aviv. Ọjọ pẹ to ti jẹ agba ọjẹ nidi imọ tẹkinọlọji – o jẹ oludasilẹ ‘Mellanox Technologies’, leyi to ta ni biliọnu mẹfa ati ẹsun mẹjọ dollar lọdun 2019. Ẹwẹ, o ti di baba to n ka ṣioṣion nitori ibanujẹ iku ọmọbinrin rẹ to kere julọ.
Pẹlu ohun ti ko ja geere to si kun fun ifẹ ati ibanujẹ lo fi wi pe “ọmọ daadaa ni. O fẹran lati maa jo. O nifẹ awọn ẹranko. O fẹran awọn eniyan. O ni ọpọlọpọ ọrẹ.o fẹran awọn ere idaraya bii wiwa ọpọn lorin yinyin, wiwẹ lọ isalẹ okun, ati lati maa gun alupupu pẹlu Noam.”

Nigba to gbọ pe Danielle sọnu, kia lo sare pada lati irinajo rẹ si Indonesia – o gba aṣẹ lati jẹki baluu rẹ o balẹ ni Israel, no tilẹ jẹ pe wọn se oju ọrun. Wakati mẹta lẹyin eyi lo jade lati lọọ waa nipasẹ aago ọwọ rẹ. Irinajo si oju ogun ni eyi jẹ.
O wi pe “a sunmọ gbigbena woju awọn agbesunmọmi abi ẹda kan, ẹ pe wọn lohun to wu yin. Wọn ti pa ọmọ-ogun bii nẹta abi mẹrin. Lẹyin eyi la ko awọn ologun mẹta sinu ọkọ jiibu taa si kọri si apa guusu”.
O ri ọkọ naa ti ibọn ti bajẹ amọ ko si Danielle nibẹ.
O ni “ẹjẹ pọ ninu ọkọ naa. Mo nireti pe ko si ninu ọkọ naa, abi ko wa nibẹ amọ ko ti salọ lẹyin to farapa, abi ko wa ni igbekun”.
Lẹyin ọjọ meji ni wọn ri oku rẹ.
Eyal, to n gbiyanju lati fi ẹkun rẹ pamọ lakoko to n sọrọ, wi pe “gbogbo ohun to ba ṣe, pẹlu ẹrin ni. Ko ṣẹ ẹnikẹni.o nifẹ si ko maa ṣe rere. Amọ wọn (Hamas) ṣeku paa lai nidi”.
Pẹlu bi wọn ṣe ṣekupa abikẹyin rẹ obinrin yii, Eyal lo ṣi nigbagbọ pe o yẹ ki Palestine ni ipinlẹ tiwọn ni kia.
“A nilo lati ṣe ayipada ijọba ni apa mejeeji. Lẹyin eyi, ni nkan bii ọdun meji si mẹrin, a maa lee gbe igbesẹ alaafia, ki as i kọ orilẹede mejeeji fun awọn eeyan mejeeji, ka si maa gbe pọ ni alaafia lẹgbẹ ara wa” ni Eyal wi.
Amọ ṣaaju eyi, Eyal fẹ nkankan.
O wi pe “ẹnikẹni to ba kopa tabi lọwọ ninu ohun to ṣẹlẹ lọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2023 gbọdọ lọ sii. A maa moju to eleyi.
“A mọ awọn to wa, to fipa bani lopọ, to pani nipakupa. A ni fanran wọn, a ni nọmna ẹrọ ilewọ wọn. A mọ ẹni ti wọn jẹ. A maa mu wọn kuro. No si lero pe a lee nu Hamas naa kuro.”

Oríṣun àwòrán, Family handout
Ajagunfẹyinti ọmọ Israel naa mọ nipa ogun. O ti ṣiṣẹ sẹyin ni aṣayan ikọ ọmọgun ti wọn pe ni ‘Golani Brigade’.
Bakan naa lo mọ nipa ifanimọra. Ṣaaju akoko yii, Eyal kọ oriko kan si Gaza, o si fi ẹgberun lona ọtalelọọdunrun dollar ran ileewosan kan lọwọ nibẹ, pẹlu ipese iṣẹ fun awọn ọmọ Palestine ni Gaza ati Wes Bank.
Njẹ Eyal kabamọ gbogbo eleyi?
“Rara o”, ni esi to fọ lai fakoko ṣofo, pẹlu afikun pe onikaluku nilo lati ṣe “gbogbo nkan to ba lee mu ki agbegbe yii jẹ ibi to rẹwa julọ lati gbe”.
“A dẹ ni lati dẹkun pipa ara wa, ki a wa ọn alati gbe ni irẹpọ. Ọdun mẹẹdọgbọn ni mo n ti ṣiṣẹ tọ alaafia nibi.”
Ọjọ mẹwaa ṣaaju ọjọ ti wọn ṣekupa Danielle lo n ba baba rẹ sọrọ nipa ọjọ ọla.
Baba rẹ ranti pe “o ni ‘baba mi, mo ti pinnu lati fẹ Noam’. Wọn ti jẹ ọrẹ fun ọdun mẹfa, to si jẹ ọrẹ to wu ni. Ilu naa ni wọn fẹẹ gbe lati tọ awọn ọmọ wọn. O fẹ ọmọ to pọ pẹlu ọpọlọpọ aja ati ẹṣin”.
Awọn ololufẹ meji naa – ti wọn ko pada raaye fẹ ara wọn – ni wọn sinku wọn papọ.












