Mo ti gbà láti jẹ́ adelé gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo - Lucky Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, Hon. Lucky Orimisan Aiyedatiwa/Facebook
Adele gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa, lo ti rọ awọn eniyan ipinlẹ naa lati tunbọ tẹra mọ adura ti wọn n ṣe fun Gomina Oluwarotimi Akeredolu lori ailera rẹ.
Aiyedatiwa rawọ ẹbẹ yii lakoko to n ba awọn olugbe ipinlẹ naa sọrọ fun igba akọkọ laarọ Ọjọbọ lẹyin to di adele gomina.
Ninu ọrọ rẹ si awọn olugbe ipinlẹ naa, Aiyedatiwa sọ pe alaafia Akeredolu ṣe pataki nitori o jẹ akinkanju olori to mu ayipada rere ba ipinlẹ naa.
O ni “gẹgẹ bi ijọba, a gba pe awọn to dibo fun wa wọle sipo ṣe pataki, a si kabamọ gbogbo ipa ti awọn nnkan to ṣẹlẹ sẹyin ni lori awọn araalu ati idagbasoke ipinlẹ yii.
Ṣaaju ni ọrọ bi Lucky Aiyedatiwa yoo ṣe jẹ adele gomina ipinlẹ Ondo, ti fa ede aiyede nipinlẹ naa, paapaa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress.
Koda, Aarẹ Bola Tinubu ba wọn da si ọrọ naa, ko to o di pe o yanju.
Ṣugbọn, ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejila, oṣu Kejila, ọdun 2023, ni Akọwe gomina ipinlẹ naa, Richard Olatunde, kede pe Gomina Akeredolu ti fọwọ si ki Aiyedatiwa dele de e, bo ṣe n lọ fun itọju ara rẹ.
Ọjọru ọjọ kẹtala oṣu kejila, odun 2023, si ni Ọgbẹni Lucky Aiyedatiwa ti bẹrẹ iṣakoso gẹgẹ bi adele gomina.
Nigba to kede iyansipo rẹ, akọwe fun Gomina Rotimi Akeredolu,Richard Olatunde, sọ pe gomina n lọ fun isinmi lati lọọ tọ ju ara rẹ, leyi ti yoo mu ki igbakeji rẹ o dele fun un.
Adele gomina naa tẹsiwaju pe oun nigbagbọ pe oṣelu awaarawa ri ẹkọ gidi kọ ninu ohun to ṣẹlẹ yii.
"Fun awa ijọba, gbogbo ohun to ṣẹlẹ yii lo yẹ ko ṣi aaye tuntun lọkan wa ti a o fi mọ riri igbagbọ tawọn eniyan ni ninu wa taa o si loo fun igbayegbadun ọpọ eniyan.
“A ni lati foju fo idaamu ari rogbodiyan to ti rekọja ki a si gbaruku ti ṣiṣẹ iṣẹ sin awọn araalu nitori afunṣọ lasan ni a jẹ.
“Ana ti re kọja. Asiko ti to lati tẹsiwaju pẹlu ifẹ, iṣọkan, ati afojusun to lọọrin ti gomina ipinlẹ yii ni.
“Mo waa bẹ gbogbo awọn to wa ni iṣejọba ipinlẹ Ondo fun atilẹyin tootọ, ajọṣepọ to yaayi ati ifarajin. A nilo irẹpọ tuntun lati lee lepa ero rere gomina ki a si muu wa si imuṣẹ.
Wahala ti kọ́kọ́ waye lori ọ̀rọ̀ naa
“Iwe apinlẹkọ latọwọ gomina nipa isinmi yii ti yoo si fi fi agbaara silẹ nibamu pẹlu ofin orilẹede Naijiria ni yoo fi ṣọwọ sile aṣofin.
“lakoko ti Gomina Akeredolu ko fi nii si nile, igbakeji gomina, Lucky Orimisan Aiyedatiwa, ni yoo maa ṣe gbogbo ojuṣe gomina bii adele.
“Gomina Akeredolu dupẹ lọwọ awọ eeyan ipinlẹ Ondo fun atilẹyin ti ifẹ wọn. O si n fi dawọn loju pe iṣejọba ohun ko nii jakan lọna idagbasoke ati itẹsiwaju to n tọ.”
Ṣaaju igbesẹ yii ni ariwo ti gba igboro ipinlẹ latọwọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako pe ki Akeredolu o gbejọba silẹ fun igbakeji rẹ, ko si gbajumọ bi yoo ṣe lalaafia.
Bakan naa ni awọn kan ti wọn jẹ alatilẹyin fun igbakeji gomina naa n beere fun igbalaaye labẹ ofin lati sọọ di adele gomina.
Ẹwe, awọn kan to jẹ alatilẹyin Akeredolu ni wọn wi pe ko si ohun ti yoo mu Akeredolu gbe ijọbasilẹ fun igbakeji rẹ nitori pe o ṣi ni alaafia to lati tẹsiwaju gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa.












