Workers Strike: Léyìn ọsẹ méjì, a máa gùnle ìyanṣẹ lódì

Oríṣun àwòrán, Labour page
Ajọ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria ti gun ijọba apapọ ni kẹṣẹ ikilọ lati gunle iyanṣẹ lodi.
Awọn Oṣiṣẹ yii ni wọn sọ ọrọ yii ninu iwe ti wọn fi lede lọjọru ọsẹ yii.
Ninu atẹjade kan ti alaga ajọ awọn oṣiṣẹ naa fọwọ si, Ayuba Wabba ni Abuja, lo ti sọ ọ.
Alaga naa ti oun ati ojugba rẹ leka awọn oniṣowo, Quadri Ọlaleyẹ ati alaga awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ, Simion Anchaver jọ fẹnuko lori iyanṣẹlọdi naa ti wọn kede rẹ si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa yii tijọba ko ba ṣe ohun to yẹ lasiko.
Gbogob wọn ti jọ fi ohun ṣọkan wi pe, n ṣe ni Ijọba apapọ n fa ọrọ naa nilẹ ti wọn si n jẹ ki o pẹ ju.
Gbogbo awọn alaga oṣiṣẹ naa wa fun Ijọba apapọ ni gbendeke ọjọ kẹrindinlogun oṣu yii lati ṣe ẹtọ.

Oríṣun àwòrán, @others
Wọn pinnu lati gunle iyanṣẹ lodi ti Ijọba ko ba tete fi wọrọkọ ṣada.
Lara ohun ti awọn oṣiṣẹ naa tẹpẹlẹ mọ ni wi pe, niwọn igba ti ele owo ori epo ti ga soke, o yẹ ki afikun ba owo oṣu.
Wọn ni ere gọbọi ti ba fifikun jala owo epo ti Ijọba si n jẹ to ida ọgọta ere.
Wọn wa ni pe, awuruju wa ninu bi Ijọba ṣe ṣafikun si owo oṣu oṣiṣẹ lati akasọ keje si ikẹrinla ti o jẹ bii ida mẹfa.

Oríṣun àwòrán, @others
Apapọ ajọ Oṣiṣẹ naa ti wa fi imọ ṣọkan lati sọ fun ijọba pe, ko si aridaju ibaṣepọ laarin wọn ati ijọba ti ijọba ko ba tẹ ara ilu lọrun.













