Nigeria Custom: Ilééṣẹ́ Aṣọ́bodè Naijiria n pa bílíọ̀nù N5.8 wọlé lójúmọ́

Ali

Oríṣun àwòrán, @Hameed

Àkọlé àwòrán, Naijiria ti n jere pupọ lati igba ti a ti ti ẹnu ibode wa pa

Oga agba pata fun ileeṣẹ Aṣọbode Naijiria, Hameed Ali ti kede pe ileeṣẹ naa n pa biliọnu mẹrin le si biliọnu mẹfa naira to din lẹgbẹrun lọna igba wọle lojoojumọ.

O ni kete ti ijọba Naijiria ti ẹnu bode rẹ pa ni awọn ti n pa owo yii wọle sapo ijọba apapọ bayii.

Lọjọ ru ni Ali sọrọ yii lasiko to n dahun ibeere lọdọ awọn ọmọ igbimọ to n mojuto eto iṣunna lọdun 2020-2022.

Loṣu kẹjọ ọdun yii ni ijoba Naijiria ti ẹnu ibode rẹ pa pẹlu awọn orilẹ-ede to mule tii bii Benin Republic.

Ijọba Naijiria ni awọn gbe igbesẹ yii lati mu ẹdinku ba awọn to n ṣe fayawọ ọja wọle.

Hameed Ali ṣalaye pe owo naa n wọle nitori pe ẹnikẹni to ba fẹ ko ọja wọ Naijiria ko ni abuda lẹyin ọpẹ ju ko san owo ẹnu ibode lọ.

Ali ni ẹru kọkọ ba oun nigba ti a tilẹkun ẹnubode wa pe boya owo ti a n pa wọle a dinku ṣugbọn idakeji lo pada ja si fun ijọba Naijiria.

Àkọlé fídíò, Badagry ní ogún àjogúnbá tó pọ̀ yàtọ̀ sí òwò ẹrú

Hameed ni koda, lọjọ kan loṣu to kọja, owo ti a pa wọle le ni biliọnu mẹsan an naira lọjọ kan ṣoṣo.

Ohun ti a tun ri ni pe awọn ọja ti wọn n ko wọle lati orilẹ-ede Benin ni wọn yoo fayawọ rẹ wọ Naijiria laisan owo ẹnibode rara.

Ali ni kete ti a ti ti ẹnubode wa pa, wọn ko ni ọna miran ju ki wọn gbe ọja wọn gba Apapa tabi TinCan Island ki a si gba owo to yẹ lori ọja naa.

Bakan naa la tun ti rii pe, odiwọn iye epo béntiroo ti awọn eniyan Naijiria n lo lojumọ naa ti dinku.

Àkọlé fídíò, Iya Woli: Ẹ̀mí ìjókíjó, Wòó, Ṣọ̀kí, Wojú, Ṣàkùṣákù, One Corner...jáde!

Oga agba aṣọbode fidiẹ mulẹ pe o to iwọn miliọnu mẹwaa o le jala epo meji to ti dinku ninu odiwọn epo bẹntiroo ti awọn eniyan Naijiria n lo.

O ni eyi fihan pe epo rọbi yii ni wọn n ji gbe lọ si Benin lọna aitọ.

Ali mẹnuba ọpọ awọn ile epo to wa loju ọna ẹnubode bii Ilaro, Idi iroko ati awọn ilu si ileto ẹnu bode Naijiria.

Ni eyi ti a ti ri ẹri pe wọn ji epo rọbi ko lọ sita.

Àkọlé fídíò, Nigeria Independence Day: Sé ẹ mọ̀ pé ọdún 1956 ló yẹ́ ká ti dòmìnira ṣùgbọ́n....