Lẹkki: Araalu gbanajẹ lori afikun owo ibode

Ọpọlọpọ eniyan tu s'ita lagbegbe Lẹkki nibilẹ eti ọsa lati fẹhonuhan lori afinku owo irinna ẹnu ibode (Toll gate) ninpinlẹ Eko lọjọ ẹti.
Akọroyin BBC, Adedayo Okedare ti o jade pẹlu awọn ogunlọgọ eniyan ti o tu jade fẹhonuhan sọ wipe inu awọn ko dun si afikun ti ijọba se fun owo irinna yii ati wipe o jẹ ipalara fun awọn olugbe adugbo lekki ati Ajah ti wọn maa nlo awọn ibusọ wọn yii lojoojumọ.

Adari awọn afẹhonuhan, Dotun Hassan salaye wipe o jẹ ohun ibanujẹ fun awọn olugbe lori ijọba awarawa nipinlẹ eko fun ijọba ati igbimọ ti o n risi eto irinna jadejado ipinlẹ yii lati fi kun owo irinna.
Ọgbẹni Hassan sọ siwaju wipe o jẹ iwa ti ko bojumu fun ijọba ati wipe o n fa irora fun awọn eniyan.
Nigbati akọroyin wa se abẹwo si ile iṣẹ ti o n se amojuto ati akoso eto irinna, ko si ẹni ti o dahun ibeere akọroyin wa.









