Presidency: $500 mílíọ́nù ni a ti ná lórí nǹkan ogun nínú owó tí a gbà nínú àṣùwọ̀n àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency
Ileeṣẹ aarẹ lorilẹ̀ede Naijiria ti sọ wi pe oun o mọ oun pupọ lori bi ijọba se na iye owo biliọnu kan Naira ti ijọba yọ ninu apo isuna lọdun 2017, fun ipese ohun ija fun ile isẹ ologun Naijiria.
Agbẹnusọ fun aarẹ orilẹede Naijria, Garba Shehu ṣalaye, lasiko to n se ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba, pe ohun kan ti oun mọ ni pe idaji owo naa ni awọn ti fi ra ohun ija lati orilẹede Amẹrika, sugbọn oun yoo bere bi wọn se na iyoku.
Agbẹnusọ fun aarẹ Buhari naa ti ni irọ ni pe awọn ọmọogun Naijiria ko ni oun ija ti wọn nilo lati koju ikọ Boko Haram.
O ni ile isẹ ọmọogun Naijiria ni awọn ohun ija igbalode bii "super tonados" ti o tilẹ le sisẹ lalẹ ti yoo si koju awọn ikọ Boko Haram naa.
Amọ, o fikun wi pe ikọ awọn ọmọ ogun ofurufu, ikọ ọmọogun ilẹ ati ti oju omi gbọdọ fọwọsowọpọ lati koju ikọ Boko Haram to n pa awọn ọmọogun ni agbeegbe Borno.
Ìpínlẹ̀ 10, ìjọba ìbílẹ̀ 24 ni Borno la gbà lọ́wọ́ Boko Haram
Agbẹnusọ fun ijọba orilẹede Naijiria, Garba Shehu fikun wipe nigba ti ijọba Buhari gba ijọba ni ọdun 2015, Boko Haram wa ni ipinlẹ mẹwa, ti wọn si ti gba ijọba ibilẹ mẹrinlelogun ni ipinlẹ Borno.
"Amọ nibayii, ko si agbeegbe kan kan ti Boko Haram wa mọ, ilu perete to wa lẹkun ibode Naijiria ni Lake Chad nikan ni wọn ti n sọse bayii".
Garba Shehu fikun wi pe ijọba Naijiria n sisẹ papọ pẹlu awọn orilẹede bii Niger, Chad, Cameroon ati Benin Republic lati ri wi pe eto abo to muna doko wa lawọn ibode orilẹede kan si omiran ki awọn ikọ Boko Haram ma baa ri ibi sa pamọ si.













